Jona 2:1-9
1
Nígbà náà ni Jona gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ láti inú ẹja náà wá,
2
Ó sì wí pé: “Nínú ìpọ́njú mi ni mo kígbe sí Olúwa, òun sì gbọ́ ohùn mi. Mo kígbe láti inú ipò òkú, mo pè fún ìrànwọ́, ìwọ sì gbọ́ ohùn mi.
3
Nítorí tí ìwọ ti sọ mí sínú ibú, ní àárín Òkun, ìṣàn omi sì yí mi káàkiri; gbogbo bíbì omi àti rírú omi rékọjá lórí mi.
4
Nígbà náà ni mo wí pé, ‘A ta mí nù kúrò níwájú rẹ; ṣùgbọ́n síbẹ̀ èmi yóò tún máa wo ìhà tẹmpili mímọ́ rẹ.’
5
Omi yí mi káàkiri, àní títí dé ọkàn; ibú yí mi káàkiri, a fi koríko odò wé mi lórí.
6
Èmi sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìsàlẹ̀ àwọn òkè ńlá; ilẹ̀ ayé pẹ̀lú ìdènà rẹ̀ yí mi ká títí: ṣùgbọ́n ìwọ ti mú ẹ̀mí mi wá sókè láti inú ibú wá, Olúwa Ọlọ́run mi.
7
“Nígbà tí ó rẹ ọkàn mi nínú mi, èmi rántí rẹ, Olúwa, àdúrà mi sì wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, nínú tẹmpili mímọ́ rẹ.
8
“Àwọn tí ń fàmọ́ òrìṣà èké kọ àánú ara wọn sílẹ̀.
9
Ṣùgbọ́n èmi yóò fi orin ọpẹ́, rú ẹbọ sí ọ. Èmi yóò san ẹ̀jẹ́ tí mo ti jẹ́. ‘Ìgbàlà wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa.’ ”
Settings