Skip to content
Johanu 18:15-27

Johanu 18:15-27

15
Simoni Peteru sì ń tọ Jesu lẹ́yìn, àti ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn kan: ọmọ-ẹ̀yìn náà jẹ́ ẹni mí mọ̀ fún olórí àlùfáà, ó sì bá Jesu wọ ààfin olórí àlùfáà lọ.
16
Ṣùgbọ́n Peteru dúró ní ẹnu-ọ̀nà lóde. Nígbà náà ni ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn náà tí í ṣe ẹni mí mọ̀ fún olórí àlùfáà jáde, ó sì bá olùṣọ́nà náà sọ̀rọ̀, ó sì mú Peteru wọlé.
17
Nígbà náà ni ọmọbìnrin náà tí ń ṣọ́ ẹnu-ọ̀nà wí fún Peteru pé, “Ìwọ pẹ̀lú ha ń ṣe ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ọkùnrin yìí bí?” Ó wí pé, “Èmi kọ́.”
18
Àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ àti àwọn aláṣẹ sì dúró níbẹ̀, àwọn ẹni tí ó ti dáná nítorí ti òtútù mú, wọ́n sì ń yáná, Peteru sì dúró pẹ̀lú wọn, ó ń yáná.
19
Nígbà náà ni olórí àlùfáà bi Jesu léèrè ní ti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, àti ní ti ẹ̀kọ́ rẹ̀.
20
Jesu dá a lóhùn pé, “Èmi ti sọ̀rọ̀ ní gbangba fún aráyé; nígbà gbogbo ni èmi ń kọ́ni nínú Sinagọgu, àti ní tẹmpili níbi tí gbogbo àwọn Júù ń péjọ sí, èmi kò sì sọ ohun kan ní ìkọ̀kọ̀.
21
Èéṣe tí ìwọ fi ń bi mí léèrè? Béèrè lọ́wọ́ àwọn tí ó ti gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, ohun tí mo wí fún wọn: wò ó, àwọn wọ̀nyí mọ ohun tí èmi wí.”
22
Bí ó sì ti wí èyí tan, ọ̀kan nínú àwọn aláṣẹ tí ó dúró tì í fi ọwọ́ rẹ̀ lu Jesu, pé, “Alábojútó àlùfáà ni ìwọ ń dá lóhùn bẹ́ẹ̀?”
23
Jesu dá a lóhùn pé, “Bí mo bá sọ̀rọ̀ búburú, jẹ́rìí sí búburú náà, ṣùgbọ́n bí rere bá ni, èéṣe tí ìwọ fi ń lù mí?”
24
Nítorí Annasi rán an lọ ní dídè sọ́dọ̀ Kaiafa olórí àlùfáà.
25
Ṣùgbọ́n Simoni Peteru dúró, ó sì ń yáná. Nígbà náà ni wọ́n wí fún un pé, “Ìwọ pẹ̀lú ha jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀?” Ó sì sẹ́, wí pé, “Èmi kọ́.”
26
Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ olórí àlùfáà, tí ó jẹ́ ìbátan ẹni tí Peteru gé etí rẹ̀ sọnù, wí pé, “Èmi ko ha rí ọ pẹ̀lú rẹ̀ ní àgbàlá?”
27
Peteru tún sẹ́: lójúkan náà àkùkọ sì kọ.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options