Jobu 39:9-25
9
“Àgbáǹréré ha jẹ́ sìn ọ́ bí? Tàbí ó jẹ́ dúró ní ibùjẹ ẹran rẹ ní òru?
10
Ìwọ le fi òkun tata de àgbáǹréré nínú aporo? Tàbí ó jẹ́ máa fa ìtulẹ̀ nínú aporo oko tọ̀ ọ́ lẹ́yìn?
11
Ìwọ ó gbẹ́kẹ̀lé e nítorí agbára rẹ̀ pọ̀? Ìwọ ó sì fi iṣẹ́ rẹ lé e lọ́wọ́?
12
Ìwọ le gbẹ́kẹ̀lé pé, yóò mú èso oko rẹ̀ wá sílé, àti pé yóò sì kó ọ jọ sínú àká rẹ?
13
“Ìwọ ni yóò ha fi ìyẹ́ dáradára fún ọ̀kín bí, tàbí ìyẹ́ àti ìhùhù bo ògòǹgò?
14
Ó yé ẹ̀yìn rẹ̀ sílẹ̀ lórí ilẹ̀, a sì mú wọn gbóná nínú ekuru;
15
tí ó sì gbàgbé pé, ẹsẹ̀ lè tẹ̀ wọ́n fọ́, tàbí pé ẹranko igbó lè tẹ̀ wọ́n fọ́.
16
Kò ní àánú sí àwọn ọmọ rẹ̀ bí ẹni pé wọn kì í ṣe tirẹ̀; asán ni iṣẹ́ rẹ̀ láìní ìbẹ̀rù;
17
nítorí pé Ọlọ́run kò fún un ní ọgbọ́n, bẹ́ẹ̀ ni kò sì fi ìpín òye fún un.
18
Nígbà tí ó gbé ara sókè, ó gan ẹṣin àti ẹlẹ́ṣin.
19
“Ìwọ ni ó fi agbára fún ẹṣin bí, tàbí ṣé ìwọ ni ó fi gọ̀gọ̀ wọ ọrùn rẹ̀ ní aṣọ?
20
Ìwọ le mú fò sókè bí ẹlẹ́ǹgà? Ògo èémí imú rẹ ní ẹ̀rù ńlá.
21
Ó fi ẹsẹ̀ halẹ̀ nínú àfonífojì, ó sì yọ̀ nínú agbára rẹ̀; ó lọ jáde láti pàdé àwọn ìhámọ́ra ogun.
22
Ó fi ojú kékeré wo ẹ̀rù, àyà kò sì fò ó; bẹ́ẹ̀ ni kì í sì í padà sẹ́yìn kúrò lọ́wọ́ idà.
23
Lọ́dọ̀ rẹ ni apó-ọfà ń mì pẹkẹpẹkẹ, àti ọ̀kọ̀ dídán àti àpáta.
24
Ó fi kíkorò ojú àti ìbínú ńlá gbé ilé mi, bẹ́ẹ̀ ni òun kò sì gbà á gbọ́ pé, ìró ìpè ni.
25
Ó wí nígbà ìpè pé, Háà! Háà! Ó sì gbóhùn ogun lókèèrè réré, igbe àwọn balógun àti ìhó ayọ̀ ogun wọn.
Settings