Skip to content
Jobu 38:22-35

Jobu 38:22-35

22
“Ìwọ ha wọ inú ìṣúra ìdì òjò lọ rí bí, ìwọ sì rí ilé ìṣúra yìnyín rí,
23
tí mo ti fi pamọ́ de ìgbà ìyọnu, dé ọjọ́ ogun àti ìjà?
24
Ọ̀nà wo ni ó lọ sí ibi tí ìmọ́lẹ̀ fi ń la, tí afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn ń tàn káàkiri lórí ilẹ̀ ayé?
25
Ta ni ó la ipadò fún ẹ̀kún omi, àti ọ̀nà fún mọ̀nàmọ́ná àrá,
26
láti mú u rọ̀jò sórí ayé níbi tí ènìyàn kò sí, ní aginjù níbi tí ènìyàn kò sí;
27
láti mú ilẹ̀ tútù, ijù àti aláìro láti mú àṣẹ̀ṣẹ̀yọ ewéko rú jáde?
28
Òjò ha ní baba bí? Tàbí ta ni o bí ìkún ìṣe ìrì?
29
Láti inú ta ni ìdì omi ti jáde wá? Ta ni ó bí ìrì dídì ọ̀run?
30
Nígbà tí omi di líle bí òkúta, nígbà tí ojú ibú ńlá sì dìpọ̀.
31
“Ìwọ ha le fi ọ̀já de àwọn ìràwọ̀ Pleiadesi dáradára? Tàbí ìwọ le tún di ìràwọ̀ Orioni?
32
Ìwọ le mú àwọn àmì méjìlá ìràwọ̀ Masaroti jáde wá nígbà àkókò wọn? Tàbí ìwọ le ṣe amọ̀nà Beari pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀?
33
Ǹjẹ́ ìwọ mọ ìlànà ọ̀run? Ìwọ le fi ìjọba Ọlọ́run lélẹ̀ lórí ayé?
34
“Ìwọ le gbé ohùn rẹ sókè dé àwọsánmọ̀ kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi kí ó lè bò ọ́?
35
Ìwọ le rán mọ̀nàmọ́ná kí wọn kí ó le lọ, ní ọ̀nà wọn kí wọn kí ó sì wí fún wọn pé, ‘Àwa nìyí’?
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options