Skip to content
Jobu 37:10-20

Jobu 37:10-20

10
Nípa ẹ̀mí Ọlọ́run a fi ìdí omi fún ni, ibú omi á sì súnkì.
11
Pẹ̀lúpẹ̀lú ó fi omi púpọ̀ mú àwọsánmọ̀ wúwo, a sì tú àwọsánmọ̀ ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ ká ara wọn.
12
Àwọn wọ̀nyí yí káàkiri nípa ìlànà rẹ̀, kí wọn kí ó lè ṣe ohunkóhun tí ó pàṣẹ fún wọn lórí ilẹ̀ ayé.
13
Ó mú àwọsánmọ̀ wá, ìbá ṣe fún ìkìlọ̀, tàbí omi wá sí ayé láti fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn.
14
“Jobu, dẹtí sílẹ̀ sí èyí; dúró jẹ́ẹ́ kí o sì ro iṣẹ́ ìyanu Ọlọ́run.
15
Ṣe ìwọ mọ àkókò ìgbà tí Ọlọ́run ṣe wọ́n lọ́jọ̀, tí ó sì mú ìmọ́lẹ̀ àwọsánmọ̀ rẹ̀ dán?
16
Ṣé ìwọ mọ ìgbà tí àwọsánmọ̀ í fò lọ, iṣẹ́ ìyanu ẹni tí ó pé ní ìmọ̀?
17
Ìwọ ẹni ti aṣọ rẹ̀ ti máa n gbóná, nígbà tí ó fi atẹ́gùn ìhà gúúsù mú ayé dákẹ́.
18
Ìwọ ha ba tẹ́ pẹpẹ ojú ọ̀run, tí ó dúró ṣinṣin, tí ó sì dàbí dígí tí ó yọ̀ dà?
19
“Kọ́ wa ní èyí tí a lè wí fún un; nítorí pé àwa kò le wádìí ọ̀rọ̀ náà nítorí òkùnkùn wa.
20
A ó ha wí fún un pé, èmi fẹ́ sọ̀rọ̀? Tàbí ẹnìkan lè wí pé, ìfẹ́ mi ni pé kí a gbé mi mì?
Settings

Reading style

Typeface

Font size 19px

Reading width 75 chars

Options