Skip to content
Jeremiah 8:4-8

Jeremiah 8:4-8

4
“Wí fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “ ‘Bí ènìyàn bá ṣubú lulẹ̀, wọn kì í padà dìde bí? Nígbà tí ènìyàn bá yà kúrò ní ọ̀nà rẹ, kì í yí padà bí?
5
Èéṣe nígbà náà àwọn ènìyàn wọ̀nyí fi yà kúrò lọ́nà rẹ̀? Kí ló dé tí Jerusalẹmu fi yà kúrò ní gbogbo ìgbà? Wọ́n rọ̀ mọ́ ẹ̀tàn; wọ́n kọ̀ láti yípadà.
6
Mo ti fetísílẹ̀ dáradára, wọn kò sọ ohun tí ó tọ́. Kò sí ẹnìkan tó ronúpìwàdà nínú ìwà búburú rẹ̀, kí ó wí pé, “Kí ni mo ṣe?” Olúkúlùkù ń tọ ọ̀nà rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹṣin tó ń lọ sójú ogun.
7
Kódà, ẹyẹ àkọ̀ ojú ọ̀run mọ ìgbà tirẹ̀, àdàbà, alápáǹdẹ̀dẹ̀ àti lékèélékèé mọ àkókò ìṣípò padà wọn. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mi kò mọ ohun tí Olúwa wọn fẹ́.
8
“ ‘Báwo ni ẹ̀yin ṣe lè wí pé, “Àwa gbọ́n, nítorí a ní òfin Olúwa,” nígbà tí ó jẹ́ pé kálámù èké àwọn akọ̀wé ti àwọn sọ ọ́ di ẹ̀tàn.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options