Skip to content
Jeremiah 8:4-7

Jeremiah 8:4-7

4
“Wí fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “ ‘Bí ènìyàn bá ṣubú lulẹ̀, wọn kì í padà dìde bí? Nígbà tí ènìyàn bá yà kúrò ní ọ̀nà rẹ, kì í yí padà bí?
5
Èéṣe nígbà náà àwọn ènìyàn wọ̀nyí fi yà kúrò lọ́nà rẹ̀? Kí ló dé tí Jerusalẹmu fi yà kúrò ní gbogbo ìgbà? Wọ́n rọ̀ mọ́ ẹ̀tàn; wọ́n kọ̀ láti yípadà.
6
Mo ti fetísílẹ̀ dáradára, wọn kò sọ ohun tí ó tọ́. Kò sí ẹnìkan tó ronúpìwàdà nínú ìwà búburú rẹ̀, kí ó wí pé, “Kí ni mo ṣe?” Olúkúlùkù ń tọ ọ̀nà rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹṣin tó ń lọ sójú ogun.
7
Kódà, ẹyẹ àkọ̀ ojú ọ̀run mọ ìgbà tirẹ̀, àdàbà, alápáǹdẹ̀dẹ̀ àti lékèélékèé mọ àkókò ìṣípò padà wọn. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mi kò mọ ohun tí Olúwa wọn fẹ́.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options