Skip to content
Jeremiah 41:11-18

Jeremiah 41:11-18

11
Nígbà tí Johanani ọmọkùnrin Karea àti gbogbo àwọn olórí ogun tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀ gbọ́ nípa gbogbo ìpànìyàn náà tí Iṣmaeli ọmọ Netaniah ti ṣe.
12
Wọ́n kó gbogbo àwọn ọkùnrin wọn, wọ́n sì, lọ bá Iṣmaeli ọmọ Netaniah jà. Wọ́n pàdé rẹ̀ ní odò kan lẹ́bàá Gibeoni.
13
Nígbà tí gbogbo àwọn ènìyàn Iṣmaeli tí wọ́n wà pẹ̀lú rẹ̀ rí Johanani ọmọkùnrin Karea àti àwọn olórí ogun rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n sì yọ̀.
14
Gbogbo àwọn ènìyàn tí Iṣmaeli ti kó ní ìgbèkùn ní Mispa yípadà, wọ́n sì lọ sọ́dọ̀ Johanani ọmọ Karea.
15
Ṣùgbọ́n Iṣmaeli ọmọkùnrin Netaniah àti àwọn mẹ́jọ nínú àwọn ọkùnrin rẹ̀ bọ́ lọ́wọ́ Johanani, wọ́n sì sálọ sí Ammoni.
16
Lẹ́yìn náà Johanani ọmọkùnrin Karea àti gbogbo àwọn ọmọ-ogun tí wọn wà pẹ̀lú rẹ̀ sì kó gbogbo àwọn tí ó kù ní Mispa; àwọn tí ó ti rí gbà lọ́wọ́ Iṣmaeli ọmọkùnrin Netaniah; lẹ́yìn ìgbà tí ó ti pa Gedaliah ọmọ Ahikamu. Àwọn ọmọ-ogun, àwọn obìnrin, àwọn ọmọdé àti àwọn olórí ilé ẹjọ́ tí ó ti kó wa láti Gibeoni.
17
Wọ́n sì kúrò níbẹ̀, wọ́n dúró ní Geruti Kimhamu ní ẹ̀bá Bẹtilẹhẹmu ní ọ́nà ìrìnàjò wọn sí Ejibiti.
18
Láti gba àwọn Babeli sílẹ̀. Wọ́n bẹ̀rù wọn nítorí wí pé, “Iṣmaeli ọmọ Netaniah ti pa Gedaliah ọmọ Ahikamu èyí tí ọba Babeli ti yàn gẹ́gẹ́ bí i gómìnà lórí ilẹ̀ náà.”
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options