Skip to content
Jeremiah 39:1-14

Jeremiah 39:1-14

1
Ó sì ṣe, nígbà tí a kó Jerusalẹmu, ní ọdún kẹsànán Sedekiah, ọba Juda, nínú oṣù kẹwàá, Nebukadnessari ọba Babeli gbógun ti Jerusalẹmu pẹ̀lú gbogbo ogun rẹ̀, wọ́n sì dó tì í.
2
Ní ọjọ́ kẹsànán, oṣù kẹrin ọdún kọkànlá Sedekiah, ni a wó odi ìlú náà.
3
Nígbà náà ni gbogbo àwọn ìjòyè ọba Babeli wá, wọ́n sì jókòó ní àárín ẹnu ibodè, àní Nergali-Ṣareseri ti Samgari, Nebo-Sarsikimu olórí ìwẹ̀fà, Nergali-Ṣareseri, olórí amòye, pẹ̀lú gbogbo àwọn ìjòyè ọba Babeli yóò kú.
4
Nígbà tí Sedekiah ọba Juda àti àwọn ọmọ-ogun rí wọn, wọ́n sá, wọ́n kúrò ní ìlú ní alẹ́, wọ́n gba ọ̀nà ọgbà ọba lọ láàrín ẹnu ibodè pẹ̀lú odi méjì, wọ́n dojúkọ aginjù.
5
Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ọmọ-ogun Babeli lé wọn, wọ́n bá Sedekiah láàrín aginjù Jeriko. Wọ́n mú un ní ìgbèkùn, wọ́n sì mú u tọ Nebukadnessari ọba Babeli àti Ribla ní ilẹ̀ Hamati, níbi tí wọ́n ti ṣe ìdájọ́ rẹ̀.
6
Níbẹ̀ ní Ribla, ni ọba Babeli ti dúńbú àwọn ọmọ Sedekiah lójú rẹ̀, tí ó sì tún pa gbogbo àwọn ọlọ́lá ilẹ̀ Juda.
7
Nígbà náà ni ó fọ́ ojú Sedekiah, ó sì dè é pẹ̀lú ẹ̀wọ̀n láti gbé e lọ sí ilẹ̀ Babeli.
8
Àwọn Babeli dáná sun ààfin ọba àti ilé àwọn ènìyàn, wọ́n sì wó odi Jerusalẹmu.
9
Nebusaradani olórí àwọn ọmọ-ogun mú lọ sí ìgbèkùn Babeli pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ó ṣẹ́kù nínú ìlú.
10
Ṣùgbọ́n Nebusaradani olórí ogun fi àwọn aláìní sílẹ̀ ní Juda, àwọn tí kò ní ohun kankan ní àkókò náà, ó fún wọn ní ọgbà àjàrà àti oko.
11
Nísinsin yìí, Nebukadnessari ọba àwọn Babeli pàṣẹ lórí Jeremiah, láti ọ̀dọ̀ Nebusaradani olórí ogun wá wí pé:
12
“Ẹ gbé e, kí ẹ sì bojútó o. Ẹ má ṣe ṣe ohun búburú fún un, ṣùgbọ́n ohunkóhun tó bá béèrè ni kí ẹ fi fún un.”
13
Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ pẹ̀lú, Nebusaradani balógun ìṣọ́, àti Nebusaradani olórí ìwẹ̀fà, àti Nergali-Ṣareseri, olórí amòye àti gbogbo àwọn ìjòyè ọba Babeli,
14
ránṣẹ́ láti mú Jeremiah kúrò nínú túbú. Wọ́n gbé e lọ fún Gedaliah ọmọ Ahikamu ọmọ Ṣafani láti mú padà lọ sí ilé àti máa wà pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Reading Width 45 chars

Options