Skip to content
Jeremiah 38:24-28

Jeremiah 38:24-28

24
Nígbà náà ni Sedekiah sọ fún Jeremiah pé, “Má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ̀ nípa ọ̀rọ̀ yìí, tàbí kí o kú.
25
Tí àwọn ìjòyè bá mọ̀ pé mo bá ọ sọ̀rọ̀, tí wọ́n bá wá bá ọ wí pé, ‘Sọ fún wa ohun tí o bá ọba sọ tàbí ohun tí ọba sọ fún ọ; má ṣe fi pamọ́ fún wa tàbí kí a pa ọ́,’
26
nígbà náà kí o sọ fún wọn, ‘Mò ń bẹ ọba láti má jẹ́ kí n padà lọ sí ilé Jonatani láti lọ kú síbẹ̀.’ ”
27
Gbogbo àwọn olóyè sì wá sí ọ̀dọ̀ Jeremiah láti bi í léèrè, ó sì sọ gbogbo ohun tí ọba ní kí ó sọ. Wọn kò sì sọ ohunkóhun mọ́, nítorí kò sí ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ tí òun àti ọba jọ sọ.
28
Jeremiah wà nínú àgbàlá àwọn ẹ̀ṣọ́ títí di ọjọ́ tí wọ́n fi kó Jerusalẹmu:
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options