Jeremiah 32:26-36
26
Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremiah wá pé:
27
“Èmi ni Olúwa Ọlọ́run gbogbo ẹran-ara. Ǹjẹ́ ohun kan ha a ṣòro fún mi bí?
28
Nítorí náà, báyìí ni Olúwa wí, Èmi ṣetán láti fi ìlú yìí fún àwọn ará Kaldea àti fún Nebukadnessari ọba Babeli ẹni tí yóò kó o.
29
Àwọn ará Kaldea tí ó ń gbógun tí ìlú yóò wọ ìlú. Wọn ó sì fi iná sí ìlú; wọn ó jó o palẹ̀ pẹ̀lú ilé tí àwọn ènìyàn ti ń mú mi bínú, tí wọ́n ń rú ẹbọ tùràrí lórí pẹpẹ fún Baali tiwọn sì ń da ẹbọ ohun mímu fún àwọn ọlọ́run mìíràn.
30
“Àwọn ènìyàn Israẹli àti Juda kò ṣe ohun kankan bí kò ṣe ibi lójú mi láti ìgbà èwe wọn. Nítorí àwọn ọmọ Israẹli ti fi kìkì iṣẹ́ ọwọ́ wọ́n mú mi bínú ni Olúwa wí.
31
Láti ọjọ́ tí wọ́n ti kọ́ ọ, títí di àkókò yìí ni ìlú yìí ti jẹ́ ohun ìbínú àti ìyọnu fún mi tó bẹ́ẹ̀ tí èmi yóò fà á tu kúrò níwájú mi.
32
Àwọn ènìyàn Israẹli àti àwọn ènìyàn Juda ti mú mi bínú pẹ̀lú gbogbo ìbàjẹ́ tí wọ́n ṣe. Àwọn Israẹli, ọba wọn àti gbogbo ìjòyè, àlùfáà àti wòlíì, àwọn ọkùnrin Juda àti àwọn ènìyàn Jerusalẹmu.
33
Wọ́n kọ ẹ̀yìn sí mi, wọ́n sì yí ojú wọn padà. Èmi kọ wọ́n, síbẹ̀ wọn kò fetísílẹ̀ láti gbọ́ ẹ̀kọ́ tàbí kọbi ara sí ìwà ìbàjẹ́.
34
Wọ́n kó òrìṣà ìríra wọn jọ sí inú ilé tí wọ́n fi orúkọ mi pè, wọ́n sì ṣọ́ di àìmọ́.
35
Wọ́n kọ́ ibi gíga fún Baali ní àfonífojì Hinnomu láti fi ọmọ wọn ọkùnrin àti obìnrin rú ẹbọ sí Moleki. Èmi kò pàṣẹ, fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni kò wá sí ọkàn mi pé kí wọ́n ṣe ohun ìríra wọ̀nyí tí ó sì mú Juda dẹ́ṣẹ̀.
36
“Ìwọ ń sọ̀rọ̀ nípa ti ìlú yìí pé, ‘Pẹ̀lú idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn ni à ó fi wọ́n fún ọba Babeli,’ ṣùgbọ́n ohun tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli sọ nìyìí,
Settings