Skip to content
Jeremiah 32:1-16

Jeremiah 32:1-16

1
Èyí ni ọ̀rọ̀ tó tọ Jeremiah wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa ní ọdún kẹwàá Sedekiah ọba Juda, èyí tí ó jẹ́ ọdún kejìdínlógún ti Nebukadnessari.
2
Àwọn ogun ọba Babeli ìgbà náà há Jerusalẹmu mọ́. A sì sé wòlíì Jeremiah mọ́ inú túbú tí wọ́n ń ṣọ́ ní àgbàlá ilé ọba Juda.
3
Nítorí Sedekiah ọba Juda ti há a mọ́lé síbẹ̀; pé, “Kí ló dé tí ìwọ fi ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀? Tí o sì wí pé, ‘Báyìí ni Olúwa wí: Èmi ń bọ̀ wá fi ìlú yìí fún ọba Babeli, tí yóò sì gbà á.
4
Sedekiah ọba Juda kò lè bọ́ lọ́wọ́ àwọn Kaldea, ṣùgbọ́n à ó mú fún ọba Babeli, yóò sì bá sọ̀rọ̀ ní ojúkojú; yóò sì rí pẹ̀lú ojú rẹ̀.
5
Yóò mú Sedekiah lọ sí Babeli tí yóò wà títí èmi yóò fi bẹ̀ ọ́ wò ni Olúwa wí. Tí ẹ̀yin bá bá àwọn ará Kaldea jà, ẹ̀yin kì yóò borí wọn.’ ”
6
Jeremiah wí pé, “Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé:
7
Hanameli ọmọkùnrin Ṣallumu ẹ̀gbọ́n rẹ̀ yóò tọ̀ ọ́ wá pé, ‘Ra pápá mi tí ó wà ní Anatoti; nítorí gẹ́gẹ́ bí ẹni tó súnmọ́ wọn, ẹ̀tọ́ àti ìṣe rẹ ní láti rà á.’
8
“Gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ, Hanameli ọmọ ẹ̀gbọ́n mi tọ̀ mí wá ní àgbàlá túbú wí pé, ‘Ra pápá mi tí ó wà ní Anatoti tí ó wà ní ilẹ̀ Benjamini, èyí tí ó jẹ́ pé ẹ̀tọ́ rẹ ni láti gbà á àti láti ni, rà á fún ara rẹ.’ “Nígbà náà ni èmi mọ̀ wí pé ọ̀rọ̀ Olúwa ni èyí.
9
Bẹ́ẹ̀ ni; èmi ra pápá náà ní Anatoti láti ọwọ́ Hanameli ọmọ ẹ̀gbọ́n mi. Mo sì wọn ìwọ̀n ṣékélì àti fàdákà mẹ́tàdínlógún fún un.
10
Mo fọwọ́ sínú ìwé, mo sì dì í pa. Mo pe ẹlẹ́rìí sí i, mo sì wọn fàdákà náà lórí òsùwọ̀n.
11
Mo mú ìwé tí mo fi rà á, èyí tí a di pa nípa àṣẹ àti òfin wa, àti èyí tí a kò lẹ̀.
12
Èmi sì fi èyí fún Baruku, ọmọ Neriah, ọmọ Maseiah, ní ojú Hanameli, ọmọ ẹ̀gbọ́n mi àti níwájú àwọn ẹlẹ́rìí tí ó ti fi ọwọ́ sí ìwé àti ní ojú àwọn Júù gbogbo tí wọ́n jókòó ní àgbàlá ilé túbú.
13
“Ní ojú wọn ni èmi ti pàṣẹ fún Baruku pé,
14
èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí; mú àwọn ìwé tí a fi rà á wọ̀nyí, àti èyí tí a lẹ̀ àti èyí tí a kò lẹ̀, kí o wá gbé wọn sínú ìkòkò amọ̀, kí wọn ó lè wà ní ọjọ́ púpọ̀.
15
Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí; àwọn ilẹ̀, pápá àti ọgbà àjàrà ni à ó tún rà padà nílẹ̀ yìí.
16
“Lẹ́yìn tí mo ti fi ìwé rírà náà fún Baruku ọmọkùnrin Neriah, mo gbàdúrà sí Olúwa wí pé:
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options