Fò sí àkóónú
Jeremiah 31:27-34

Jeremiah 31:27-34

27
“Wò ó, ọjọ́ ń bọ̀,” ni Olúwa wí, “nígbà tí èmi yóò gbin ilé Israẹli àti ilé Juda pẹ̀lú irúgbìn ọmọ ènìyàn àti ẹranko.
28
Gẹ́gẹ́ bí mo ṣe ń ṣọ́ wọn, láti fàtu, àti láti wó lulẹ̀, àti láti gba ìṣàkóso, láti bàjẹ́ àti láti mú ibi wá, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò ṣọ́ wọn láti kọ́ àti láti gbìn,” ni Olúwa wí.
29
“Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì àwọn ènìyàn kò ní sọ mọ́ pé: “ ‘Àwọn baba ti jẹ èso àjàrà àìpọ́n àti pé eyín kan àwọn ọmọdé.’
30
Ṣùgbọ́n olúkúlùkù ni yóò kú fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ èso kíkan ni eyín yóò kan.
31
“Ìgbà kan ń bọ̀,” ni Olúwa wí, “tí Èmi yóò bá ilé Israẹli àti ilé Juda dá májẹ̀mú tuntun.
32
Kò ní dàbí májẹ̀mú tí mo bá àwọn baba ńlá wọn dá, nígbà tí mo fà wọ́n lọ́wọ́, tí mo mú wọn jáde ní Ejibiti nítorí wọ́n da májẹ̀mú mi. Lóòótọ́ ọkọ ni èmi jẹ́ fún wọn,” ni Olúwa wí.
33
“Èyí ni májẹ̀mú tí èmi yóò bá ilé Israẹli dá lẹ́yìn ìgbà náà,” ni Olúwa wí pé: “Èmi yóò fi òfin mi sí ọkàn wọn, èmi ó sì kọ ọ́ sí àyà wọn. Èmi ó jẹ́ Olúwa wọn; àwọn ó sì jẹ́ ènìyàn mi.
34
Kò ní sí pé ọkùnrin kan ń kọ́ àwọn ará ilé rẹ̀ tàbí ọkùnrin ń kọ́ arákùnrin rẹ̀ pé, ‘Ẹ mọ Olúwa,’ nítorí gbogbo wọn ni yóò mọ̀ mí láti ẹni kékeré wọn títí dé ẹni ńlá,” ni Olúwa wí. “Nítorí èmi ó dárí àìṣedéédéé wọn jì, èmi kò sì ní rántí ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́.”
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Reading Width 45 chars

Options