Jeremiah 30:1-12
1
Ọ̀rọ̀ tí ó tọ Jeremiah wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá, wí pé:
2
“Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Israẹli wí, pé: ‘Ìwọ kọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo ti bá ọ sọ sínú ìwé kan.
3
Ọjọ́ ń bọ̀ nígbà tí ń ó mú àwọn ènìyàn mi, àwọn ọmọ Israẹli àti Juda kúrò nínú ìgbèkùn, tí n ó sì dá wọn padà sí orí ilẹ̀ tí mo fi fún àwọn baba ńlá wọn láti ní,’ ni Olúwa Ọlọ́run wí.”
4
Ìwọ̀nyí ni àwọn ọ̀rọ̀ Olúwa Ọlọ́run sí Israẹli àti Juda:
5
“Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “ ‘Igbe ẹ̀rù àti ìwárìrì ni a gbọ́ láìṣe igbe àlàáfíà.
6
Béèrè kí o sì rí. Ǹjẹ́ ọkùnrin le dá ọmọ bí? Èéṣe tí mo fi ń rí àwọn alágbára ọkùnrin tí wọ́n fi ọwọ́ wọn mú inú wọn bí obìnrin tó ń rọbí, tí ojú gbogbo wọ́n sì fàro fún ìrora?
7
Ọjọ́ náà yóò ha ti burú tó! Kò sí ọjọ́ tí yóò dàbí rẹ̀, Ọjọ́ náà yóò jẹ́ àkókò ìdààmú fún Jakọbu ṣùgbọ́n yóò rí ìgbàlà kúrò nínú ìdààmú náà.
8
“ ‘Ní ọjọ́ náà,’ Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé, ‘Èmi yóò gbé àjàgà kúrò lọ́rùn wọn, Èmi yóò sì tú ìdè wọn sọnù. Àwọn àjèjì kì yóò sì mú ọ sìn wọ́n mọ́.
9
Dípò bẹ́ẹ̀ wọn yóò máa sin Olúwa Ọlọ́run wọn àti Dafidi gẹ́gẹ́ bí ọba wọn, ẹni tí èmi yóò gbé dìde fún wọn.
10
“ ‘Nítorí náà, má ṣe bẹ̀rù, ìwọ Jakọbu ìránṣẹ́ mi, má sì ṣe jẹ́ kí ẹ̀rù bà ọ́, ìwọ Israẹli,’ ni Olúwa wí. ‘Èmi yóò gbà ọ́ kúrò láti ọ̀nà jíjìn wá, àní àwọn ìran rẹ láti ilẹ̀ àtìpó wọn. Jakọbu yóò sì tún ní àlàáfíà àti ààbò rẹ̀ padà, kò sì ṣí ẹni tí yóò ṣẹ̀rù bà á mọ́.
11
Èmi wà pẹ̀lú rẹ, n ó sì gbà ọ́,’ ni Olúwa wí. ‘Bí mo tilẹ̀ pa gbogbo orílẹ̀-èdè run, nínú èyí tí mo ti fọ́n ọn yín ká, síbẹ̀ èmi kì yóò pa yín run pátápátá. Èmi yóò bá yín wí pẹ̀lú ìdájọ́ òdodo nìkan; Èmi kò ní fi yín sílẹ̀ láìjìyà.’
12
“Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “ ‘Ọgbẹ́ yín kò gbóògùn, bẹ́ẹ̀ ni egbò yín kọjá ìwòsàn.
Settings