Skip to content
Jeremiah 29:24-32

Jeremiah 29:24-32

24
Wí fún Ṣemaiah tí í ṣe Nehalami pé,
25
“Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Alágbára Israẹli wí: Ìwọ fi lẹ́tà ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn ènìyàn ní Jerusalẹmu sí Sefaniah ọmọ Maaseiah tí í ṣe àlùfáà ní orúkọ mi; ó sì sọ fún Sefaniah wí pé,
26
‘Olúwa ti yàn ọ́ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà rọ́pò Jehoiada láti máa jẹ́ alákòóso ilé Olúwa, kí o máa fi èyíkéyìí nínú àwọn aṣiwèrè tó bá ṣe bí i wòlíì si inú àgò irin.
27
Nítorí náà, èéṣe tí o kò fi bá Jeremiah ará Anatoti wí. Ẹni tí ó ń dúró bí i wòlíì láàrín yín?
28
Ó ti rán iṣẹ́ yìí sí wa ni Babeli wí pé, àtìpó náà yóò pẹ́ kí ó tó parí, nítorí náà, ẹ kọ́ ilé kí ẹ sì máa gbé ibẹ̀, ẹ dá oko, kí ẹ sì máa jẹ èso ohun ọ̀gbìn oko yín.’ ”
29
Sefaniah àlùfáà ka lẹ́tà náà sí etí ìgbọ́ Jeremiah tí í ṣe wòlíì.
30
Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Jeremiah wá wí pé,
31
“Rán iṣẹ́ yìí sí gbogbo àwọn ìgbèkùn wí pé: ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí ní ti Ṣemaiah, ará Nehalami: Nítorí pé Ṣemaiah ti sọtẹ́lẹ̀ fún un yín, ṣùgbọ́n èmi kò ran an, tí òun sì ń mú u yín gbẹ́kẹ̀lé èké.
32
Nítorí náà báyìí ni Olúwa wí: Wò ó, èmi yóò bẹ Ṣemaiah, ará Nehalami wò, àti irú-ọmọ rẹ̀; òun kì yóò ní ọkùnrin kan láti máa gbé àárín ènìyàn yìí, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò rí rere náà tí èmi yóò ṣe fún àwọn ènìyàn mi ni Olúwa wí, nítorí ó ti ti kéde ìṣọ̀tẹ̀ sí mi.’ ”
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options