Skip to content
Jeremiah 29:15-23

Jeremiah 29:15-23

15
Ẹ̀yin lè wí pé, “Olúwa ti gbé àwọn wòlíì dìde fún wa ní Babeli.”
16
Ṣùgbọ́n èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa ní ti ọba tí ó jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi àti ní ti gbogbo ènìyàn tó ṣẹ́kù ní ìlú yìí; àní ní ti àwọn ènìyàn yín tí kò bá yín lọ sí ìgbèkùn,
17
bẹ́ẹ̀ ni, báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé, “Èmi yóò rán idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn sí àárín wọn; Èmi yóò ṣe wọ́n bí èso ọ̀pọ̀tọ́ búburú tí kò ṣe é jẹ.
18
Èmi yóò fi idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn lépa wọn, Èmi yóò sì sọ wọ́n di ìríra lójú gbogbo ìjọba ayé, fún ègún, àti ìyanu, àti ẹ̀sín, àti ẹ̀gàn láàrín gbogbo orílẹ̀-èdè ayé, ní ibi tí Èmi yóò lé wọn sí.
19
Nítorí wọ́n kọ̀ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ mi,” ni Olúwa Ọlọ́run wí. Ọ̀rọ̀ tí mo tún ti ẹnu àwọn ìránṣẹ́ mi wòlíì sọ ní ẹ̀yin tí ń ṣe àtìpó kò gbọ́ ni Olúwa Ọlọ́run wí.
20
Nítorí náà, gbogbo ẹ̀yin ìgbèkùn, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, ẹ̀yin tí mo rán lọ kúrò ní Jerusalẹmu lọ sí Babeli.
21
Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli sọ nípa Ahabu ọmọ Kolaiah àti nípa Sedekiah ọmọ Maaseiah tí wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké fún un yín lórúkọ mi: “Èmi yóò fi wọ́n lé Nebukadnessari ọba Babeli lọ́wọ́. Òun yóò sì gba ẹ̀mí wọn ní ìṣẹ́jú yìí gan an.
22
Nítorí tiwọn, ègún yìí yóò ran gbogbo àwọn àtìpó tó wà ní ilẹ̀ Babeli láti Juda: ‘Olúwa yóò ṣe yín bí i Sedekiah àti Ahabu tí ọba Babeli dáná sun.’
23
Nítorí wọ́n ti ṣe ibi ní ilé Israẹli, wọ́n ti ṣe àgbèrè pẹ̀lú àwọn ìyàwó aládùúgbò wọn, àti ní orúkọ mi ni wọ́n ti ṣe èké, èyí tí Èmi kò rán wọn láti ṣe. Ṣùgbọ́n, Èmi mọ àwọn nǹkan wọ̀nyí, mo sì jẹ́ ẹlẹ́rìí sí i,” ni Olúwa wí.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options