Skip to content
Jeremiah 2:5-13

Jeremiah 2:5-13

5
Báyìí ni Olúwa wí: “Irú àìṣedéédéé wo ni baba yín rí lọ́wọ́ mi, tí wọ́n fi jìnnà sí mi? Wọ́n tẹ̀lé àwọn òrìṣà asán, àwọn fúnra wọn sì di asán.
6
Wọn kò béèrè, ‘Níbo ni Olúwa wà, tí ó mú wa jáde láti ilẹ̀ Ejibiti wá, tí ó mú wa la aginjù já, tí ó mú wa la àárín pẹ̀tẹ́lẹ̀ àti ihò, ìyàngbẹ ilẹ̀ àti òkùnkùn biribiri, ilẹ̀ ibi tí ẹnikẹ́ni kò là kọjá, tí ẹnikẹ́ni kò sì tẹ̀dó sí?’
7
Èmi mú yín wá sí ilẹ̀ ọlọ́ràá láti máa jẹ èso ibẹ̀ àti ọrọ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀yin wọ inú rẹ̀, ẹ sì bà á jẹ́, ẹ sì sọ ogún mi di ohun ìríra.
8
Àwọn àlùfáà kò béèrè wí pé, ‘Níbo ni Olúwa wà?’ Àwọn tí ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú òfin kò si mọ̀ mí, àwọn olùṣọ́ sì ṣẹ̀ sí mi. Àwọn wòlíì sì ń sọtẹ́lẹ̀ nípa òrìṣà Baali, wọ́n sì ń tẹ̀lé àwọn òrìṣà asán.
9
“Nítorí náà, mo fi ẹ̀sùn kàn yín lẹ́ẹ̀kan sí i,” ni Olúwa wí. “Èmi ó sì fi ẹ̀sùn kan àwọn ọmọ ọwọ́ rẹ.
10
Rékọjá lọ sí erékùṣù àwọn ara Kittimu, kí ẹ sì wò ó, ránṣẹ́ lọ sí ìlú Kedari, kí ẹ sì kíyèsi gidigidi; kí ẹ wò bí irú nǹkan báyìí bá ń bẹ níbẹ̀?
11
Orílẹ̀-èdè kan ha á pa ọlọ́run rẹ̀ dà? (Síbẹ̀, wọ́n kì í ṣe iṣẹ́ ọlọ́run.) Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mi ti pààrọ̀ Ọlọ́run ògo wọn fún àwọn ère tí kò níyì.
12
Àwọn ènìyàn mi ti dẹ́ṣẹ̀ méjì kí ẹ sì wárìrì pẹ̀lú ìbẹ̀rù ńlá,” ni Olúwa wí.
13
“Àwọn ènìyàn mi ti dẹ́ṣẹ̀ méjì, wọ́n ti kọ̀ mí sílẹ̀, Èmi orísun omi ìyè, wọ́n sì ti ṣe àmù, àmù fífọ́ tí kò lè gba omi dúró.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options