Jeremiah 15:10-21
10
Háà! Ó ṣe tí ìyá mi bí mi, ọkùnrin tí gbogbo ilẹ̀ dojúkọ tí wọ́n sì bá jà! Èmi kò wínni, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò yá lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, síbẹ̀, gbogbo ènìyàn ló ń fi mí ré.
11
Olúwa sọ pé, “Dájúdájú èmi ò dá ọ sí fún ìdí kan pàtó; dájúdájú mo mú kí àwọn ọ̀tá rẹ tẹríba níwájú rẹ nígbà ibi àti ìpọ́njú.
12
“Ǹjẹ́ ẹnìkan lè fi ọwọ́ ṣẹ́ irin irin láti àríwá tàbí idẹ?
13
“Gbogbo ọlá àti ìṣúra rẹ ni èmi ó fi sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìkógun láìgba nǹkan kan nítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jákèjádò orílẹ̀-èdè rẹ.
14
Èmi yóò fi ọ́ ṣẹrú fún àwọn ọ̀tá rẹ ní ìlú tí ìwọ kò mọ̀ nítorí ìbínú mi yóò rán iná tí yóò jó ọ.”
15
Ó yé ọ, ìwọ Olúwa; rántí mi kí o sì ṣe ìtọ́jú mi. Gbẹ̀san mi lára àwọn tó dìtẹ̀ mi. Ìwọ ti jìyà fún ìgbà pípẹ́, má ṣe mú mi lọ; nínú bí mo ṣe jìyà nítorí tìrẹ.
16
Nígbà tí ọ̀rọ̀ rẹ dé, mo jẹ wọ́n, àwọn ni ìdùnnú àti ayọ̀ ọkàn mi, nítorí pé orúkọ rẹ ni a fi ń pè mí, Ìwọ Olúwa Ọlọ́run Alágbára.
17
Èmi kò fìgbà kan jókòó láàrín àwọn ẹlẹ́gàn, n ko bá wọn yọ ayọ̀ pọ̀; mo dá jókòó torí pé ọwọ́ rẹ wà lára mi, ìwọ sì ti fi ìbínú rẹ kún inú mi.
18
Èéṣe tí ìrora mi kò lópin, tí ọgbẹ́ mi kò sì ṣe é wòsàn? Ní òtítọ́ ìwọ yóò dàbí kànga ẹ̀tàn sí mi, gẹ́gẹ́ bí ìsun tó kọ̀ tí kò sun?
19
Nítorí náà báyìí ni Olúwa wí, “Tí o bá ronúpìwàdà, Èmi ó dá ọ padà wá kí o lè máa sìn mí; tí ó bá sọ ọ̀rọ̀ tó dára, ìwọ yóò di agbẹnusọ mi. Jẹ́ kí àwọn ènìyàn yìí kọjú sí ọ; ṣùgbọ́n ìwọ kò gbọdọ̀ kọjú sí wọn.
20
Èmi fi ọ́ ṣe odi idẹ tí ó lágbára, sí àwọn ènìyàn wọ̀nyí; wọn ó bá ọ jà ṣùgbọ́n wọn kò ní lè borí rẹ, nítorí pé, mo wà pẹ̀lú rẹ láti gbà ọ́ là, kí n sì dáàbò bò ọ́,” ni Olúwa wí.
21
“Èmi yóò gbà ọ́ sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ìkà ènìyàn, Èmi yóò sì rà ọ́ padà kúrò lọ́wọ́ àwọn ẹni búburú.”
Settings