Jeremiah 15:1-9
1
Nígbà náà ni Olúwa sọ fún mi pé: “Kódà kí Mose àti Samuẹli dúró níwájú mi, ọkàn mi kì yóò lọ sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Mú wọn kúrò níwájú mi! Jẹ́ kí wọn ó lọ!
2
Tí wọ́n bá sì bi ọ́ pé, ‘Níbo ni kí a lọ?’ Sọ fún wọn pé, ‘Báyìí ni Olúwa wí: “ ‘Àwọn tí a kọ ikú mọ́, sí ikú; àwọn tí a kọ idà mọ́, sí idà; àwọn tí a kọ ìyàn mọ́, sí ìyàn; àwọn tí a kọ ìgbèkùn mọ́ sí ìgbèkùn.’
3
“Èmi yóò rán oríṣìí ìjìyà mẹ́rin láti kọlù wọ́n,” ni Olúwa wí, “Idà láti pa, àwọn ajá láti wọ́ wọn lọ, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti àwọn ẹranko orí ilẹ̀ láti jẹ àti láti parun.
4
N ó sọ wọ́n di ẹni ìkórìíra níwájú gbogbo ìjọba ayé torí ohun tí Manase ọmọ Hesekiah ọba Juda ṣe ní Jerusalẹmu.
5
“Ta ni yóò ṣàánú rẹ, ìwọ Jerusalẹmu? Ta ni yóò dárò rẹ? Ta ni yóò dúró béèrè àlàáfíà rẹ?
6
O ti kọ̀ mí sílẹ̀,” ni Olúwa wí, “Ìwọ sì wà nínú ìpadàsẹ́yìn. Nítorí náà, Èmi yóò dáwọ́lé ọ, èmi ó sì pa ọ́ run, Èmi kò sì ní fi ojú àánú wò ọ́ mọ́.
7
Èmi kò tún lè fi ìfẹ́ hàn si ọ, Èmi yóò fi àtẹ fẹ́ wọn sí ẹnu-ọ̀nà ìlú náà. Èmi yóò mú ìṣọ̀fọ̀ àti ìparun bá àwọn ènìyàn mi nítorí pé wọn kò tí ì yípadà kúrò lọ́nà wọn.
8
Èmi yóò jẹ́ kí àwọn opó wọn pọ̀ ju yanrìn Òkun lọ. Ní ọjọ́-kanrí ni èmi ó mú apanirun kọlu àwọn ìyá ọmọkùnrin wọn. Lójijì ni èmi yóò mú ìfòyà àti ìbẹ̀rù bá wọn.
9
Ìyá ọlọ́mọ méje yóò dákú, yóò sì mí ìmí ìgbẹ̀yìn. Òòrùn rẹ yóò wọ̀ lọ́sàn án gangan, yóò di ẹni ẹ̀tẹ́ òun àbùkù. Èmi yóò fi àwọn tí ó bá yè síwájú àwọn ọ̀tá wọn tí idà wà lọ́wọ́ wọn,” ni Olúwa wí.
Settings