Isaiah 30:28-33
28
Èémí rẹ̀ sì dàbí òjò alágbára, tí ó rú sókè dé ọ̀run. Ó jọ àwọn orílẹ̀-èdè nínú kọ̀ǹkọ̀sọ̀; ó sì fi sí ìjánu ní àgbọ̀n àwọn ènìyàn láti ṣì wọ́n lọ́nà.
29
Ẹ̀yin ó sì kọrin gẹ́gẹ́ bí i ti alẹ́ tí ẹ̀ ń ṣe àjọyọ̀ àpéjọ mímọ́, ọkàn yín yóò yọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí àwọn ènìyàn gòkè lọ pẹ̀lú fèrè sí orí òkè Olúwa, àní sí àpáta Israẹli.
30
Olúwa yóò jẹ́ kí wọn ó gbọ́ ohùn ògo rẹ̀ yóò sì jẹ́ kí wọ́n rí apá rẹ̀ tí ó ń bọ̀ wálẹ̀ pẹ̀lú ìbínú gbígbóná àti iná ajónirun, pẹ̀lú mọ̀nàmọ́ná, àrá àti yìnyín.
31
Ohùn Olúwa yóò fọ́ Asiria túútúú, pẹ̀lú ọ̀pá aládé rẹ̀ ni yóò lù wọ́n bolẹ̀.
32
Ẹgba kọ̀ọ̀kan tí Olúwa bá gbé lé wọn pẹ̀lú ọ̀pá ìjẹníyà rẹ̀ yóò jẹ́ ti ṣaworo àti ti dùùrù, gẹ́gẹ́ bí ó ti ń bá wọn jà lójú ogun pẹ̀lú ìkùùkuu láti apá rẹ̀.
33
A ti tọ́jú Tofeti sílẹ̀ tipẹ́tipẹ́, a ti tọ́jú rẹ̀ sílẹ̀ fún ọba. Ojú ààrò rẹ̀ ni a ti gbẹ́ jì tí ó sì fẹ̀, pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ iná àti igi ìdáná; èémí Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ìṣàn sulfuru ń jó ṣe mú un gbiná.
Settings