Isaiah 29:9-16
9
Ẹ bẹ̀rù kí ẹnu kí ó yà yín, ẹ fọ́ ara yín lójú kí ẹ má sì ríran; ẹ mutí yó kì í ṣe ọtí wáìnì, ẹ ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n, ṣùgbọ́n kì í ṣe ti ọtí líle.
10
Olúwa ti mú oorun ìjìká wá sórí i yín: ó ti dì yín lójú ẹ̀yin wòlíì; ó ti bo orí yín ẹ̀yin aríran.
11
Fún un yín gbogbo ìran yìí kò yàtọ̀ sí àwọn ọ̀rọ̀ tí a fi èdìdì dì sínú ìwé kíká. Bí ẹ bá sì fún ẹni tí ó lè ka ìwé kíká náà, tí ẹ sì sọ fún un pé, “Jọ̀wọ́ ka èyí,” òun yóò dáhùn pé, “Èmi kò lè kà á; a ti dì í ní èdìdì.”
12
Tàbí bí ẹ bá fún ẹni tí kò lè ka ìwé kíká náà tí ẹ sì sọ pé, “Jọ̀wọ́ ka èyí,” òun yóò dáhùn pé, “Èmi kò mọ̀ ọ́n kà.”
13
Olúwa wí pé: “Àwọn ènìyàn yìí súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi pẹ̀lú ẹnu wọn, wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún mi pẹ̀lú ètè wọn, ṣùgbọ́n ọkàn wọn jìnnà sí mi. Ìsìn wọn si mi ni a gbé ka orí òfin tí àwọn ọkùnrin kọ́ ni.
14
Nítorí náà lẹ́ẹ̀kan sí i èmi yóò ya àwọn ènìyàn yìí lẹ́nu pẹ̀lú ìyanu lórí ìyanu; ọgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n ni yóò ṣègbé, ìmọ̀ àwọn onímọ̀ ni yóò pòórá.”
15
Ègbé ni fún àwọn tí ó lọ sí ọ̀gbun láti fi ètò wọn pamọ́ kúrò lójú Olúwa, tí wọ́n ń ṣe iṣẹ́ ẹ wọn nínú òkùnkùn tí wọ́n sì rò pé, “Ta ló rí wa? Ta ni yóò mọ̀?”
16
Ẹ̀yin dojú nǹkan délẹ̀, bí ẹni pé wọ́n rò pé amọ̀kòkò dàbí amọ̀! Ǹjẹ́ ohun tí a ṣe le sọ fún olùṣe pé, “Òun kọ́ ló ṣe mí”? Ǹjẹ́ ìkòkò lè sọ nípa amọ̀kòkò pé, “Kò mọ nǹkan”?
Settings