Skip to content
Isaiah 29:1-8

Isaiah 29:1-8

1
Ègbé ni fún ọ, Arieli, Arieli, ìlú níbi tí Dafidi tẹ̀dó sí! Fi ọdún kún ọdún sì jẹ́ kí àwọn àkọlùkọgbà àjọ̀dún un rẹ tẹ̀síwájú.
2
Síbẹ̀síbẹ̀ èmi yóò dó ti Arieli òun yóò ṣọ̀fọ̀ yóò sì sọkún, òun yóò sì dàbí pẹpẹ ọkàn sí mi.
3
Èmi yóò sì wà ní bùba yí ọ ká níbi gbogbo, Èmi yóò sì fi ilé ìṣọ́ yí ọ ká, Èmi yóò sì fi iṣẹ́ ìdó ti ni mi dojúkọ ọ́.
4
Ní ìrẹ̀sílẹ̀, ìwọ ó sì máa sọ̀rọ̀ láti ilẹ̀ wá; ọ̀rọ̀ rẹ yóò sì máa kùn jáde láti inú erùpẹ̀. Ohun rẹ yóò máa jáde bí i ti ẹnìkan tó ní ẹ̀mí àfọ̀ṣẹ láti ilẹ̀ jáde wá, láti inú erùpẹ̀ ni ohùn rẹ yóò máa wá wúyẹ́wúyẹ́.
5
Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀tá rẹ, yóò dàbí yanrìn kíkúnná, agbo àwọn aláìláàánú bí ìyàngbò tí a fẹ́ dànù. Lójijì, ní ìṣẹ́jú kan,
6
Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò wá pẹ̀lú àrá àti ilẹ̀-rírì àti ariwo ńlá, àti ẹ̀fúùfù líle àti iná ajónirun.
7
Lẹ́yìn náà, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ènìyàn tí gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó bá Arieli jà, tí ó dojú ìjà kọ òun àti ilé olódi rẹ̀ tí ó sì dó tì í, yóò dàbí ẹni pé nínú àlá, bí ìran ní òru
8
àti bí ìgbà tí ẹni tí ebi ń pa ń lá àlá pé òun ń jẹun, ṣùgbọ́n ó jí, ebi rẹ̀ sì wà pẹ̀lú rẹ̀; tàbí bí ìgbà tí ẹni tí òǹgbẹ ń gbẹ lá àlá pé òun ń mu omi, ṣùgbọ́n nígbà tí ó jí, sì wò ó, ó dákú, òǹgbẹ sì ń gbẹ ọkàn rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni yóò sì rí fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè tí ń bá òkè Sioni jà.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options