Skip to content
Isaiah 22:6-14

Isaiah 22:6-14

6
Elamu mú apó-ọfà lọ́wọ́, pẹ̀lú àwọn agun-kẹ̀kẹ́-ogun àti àwọn ẹṣin, Kiri yọ àpáta rẹ̀ síta.
7
Àyànfẹ́ àfonífojì rẹ kún fún kẹ̀kẹ́ ogun, àwọn ẹlẹ́ṣin ni a gbá jọ sí ẹnu-bodè ìlú.
8
Gbogbo ààbò Juda ni a ti ká kúrò. Ìwọ sì gbójú sókè ní ọjọ́ náà sí àwọn ohun ìjà ní ààfin ti inú aginjù.
9
Ìwọ rí i pé ìlú u Dafidi ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ààyè níbi ààbò rẹ̀, ìwọ ti tọ́jú omi sínú adágún ti ìsàlẹ̀.
10
Ìwọ ka àwọn ilé tí ó wà ní Jerusalẹmu ó sì wó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé lulẹ̀ láti fún ògiri lágbára.
11
Ìwọ mọ agbemi sí àárín ògiri méjì fún omi inú adágún àtijọ́, ṣùgbọ́n ìwọ kò wo ẹni tí ó ṣe é tẹ́lẹ̀ tàbí kí o kọbi ara sí ẹni tí ó gbèrò rẹ̀ ní ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn.
12
Olúwa, àní Olúwa àwọn ọmọ-ogun, pè ọ́ ní ọjọ́ náà láti sọkún kí o sì pohùnréré, kí o tu irun rẹ dànù kí o sì da aṣọ ọ̀fọ̀ bora.
13
Ṣùgbọ́n wò ó, ayọ̀ àti ayẹyẹ wà; màlúù pípa àti àgùntàn pípa, ẹran jíjẹ àti ọtí wáìnì mímu! Ẹ̀yin wí pé, “Jẹ́ kí a jẹ kí a mu, nítorí pé lọ́la àwa ó kú!”
14
Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti sọ èyí di mí mọ̀ létí ì mi: “Títí di ọjọ́ ikú yín a kò ní ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ yìí,” ni Olúwa wí, àní Olúwa àwọn ọmọ-ogun.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options