Habakuku 2:6-20
6
“Gbogbo àwọn wọ̀nyí kì yóò máa pa òwe sí i tí wọn yóò sì máa kọ orin òwe sí i wí pé, “ ‘Ègbé ni fún ẹni tí ń mu ohun tí kì í ṣe tirẹ̀ pọ̀ sí i! Tí ó sì sọ ara rẹ̀ di ọlọ́rọ̀ nípasẹ̀ ìlọ́nilọ́wọ́gbà! Eléyìí yóò ha ti pẹ́ tó?’
7
Ǹjẹ́ ẹni ti ó yọ ọ́ lẹ́nu, kí yóò ha dìde ní òjijì? Àti àwọn tí ó wàhálà rẹ kì yóò jí, kí wọn ó sì dẹ́rùbà ọ́? Nígbà náà ni ìwọ yóò wa dí ìkógun fún wọn.
8
Nítorí ìwọ ti kó Orílẹ̀-èdè púpọ̀, àwọn ènìyàn tókù yóò sì kó ọ nítorí ìwọ tí ta ẹ̀jẹ̀ ènìyàn sílẹ̀; nítorí ẹ̀jẹ̀, ìwọ tí pa ilẹ̀ àti ìlú ńlá run àti gbogbo ènìyàn to ń gbé inú rẹ̀.
9
“Ègbé ni fún ẹni tí ń jẹ èrè ìjẹkújẹ sí ilé rẹ̀, tí o sí gbé ìtẹ́ rẹ̀ lórí ibi gíga, kí a ba le gbà á sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ibi!
10
Ìwọ ti gbìmọ̀ ìtìjú sí ilé rẹ nípa kíké ènìyàn púpọ̀ kúrò; ìwọ sì ti pàdánù ẹ̀mí rẹ.
11
Nítorí tí òkúta yóò kígbe jáde láti inú ògiri wá, àti ìtí igi láti inú igi rírẹ́ wá yóò sì dá a lóhùn.
12
“Ègbé ni fún ẹni tí ó fi ẹ̀jẹ̀ kọ́ ìlú, tí o sì fi àìṣedéédéé tẹ ìlú ńlá dó?
13
Olúwa àwọn ọmọ-ogun kò ha ti ṣètò rẹ̀ pé làálàá àwọn ènìyàn jẹ́ epo fún iná kí àwọn orílẹ̀-èdè náà sì máa ṣe wàhálà fún asán?
14
Nítorí tí ayé yóò kún fún ìmọ̀ ògo Olúwa, bí omi ti bo Òkun.
15
“Ègbé ni fún ẹni tí ó fi ohun mímu fún aládùúgbò rẹ̀, tí ó sì fi ọtí-lílé rẹ̀ fún un, tí o sì jẹ́ kó mu àmupara, kí ìwọ kí ó ba lè wo ìhòhò wọn.”
16
Ìtìjú yóò bò ọ́ dípò ògo, ìwọ náà mu pẹ̀lú kí ìhòhò rẹ kí ó lè hàn, ago ọwọ́ ọ̀tún Olúwa, yóò yípadà sí ọ, ìtìjú yóò sì bo ògo rẹ.
17
Nítorí ìwà ipá tí ó tí hù sí Lebanoni yóò bò ọ́, àti ìparun àwọn ẹranko yóò dẹ́rùbà ọ́ mọ́lẹ̀. Nítorí ìwọ tí ta ẹ̀jẹ̀ ènìyàn sílẹ̀; ìwọ tí pa ilẹ̀ náà àti ìlú ńlá run àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.
18
“Èrè kí ni òrìṣà ni, tí oníṣọ̀nà rẹ̀ fi gbẹ́ ẹ, ère dídá ti ń kọ ni èké? Nítorí ti ẹni ti ó dá a gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé ohun tí ó fúnra rẹ̀ dá; ó sì mọ ère tí kò le fọhùn.
19
Ègbé ni fún ẹni ti ń sọ fún igi pé, ‘Di alààyè?’ Fún òkúta tí kò lè fọhùn pé, ‘Dìde.’ Ǹjẹ́ òun lè tọ́ ni sí ọ̀nà? Wúrà àti fàdákà ni a fi bò ó yíká; kò sì sí èémí kan nínú rẹ.”
20
Ṣùgbọ́n Olúwa wà nínú tẹmpili mímọ́ rẹ̀; ẹ jẹ́ kí gbogbo ayé parọ́rọ́ níwájú rẹ.
Settings