Gẹnẹsisi 38:6-11
6
Juda sì fẹ́ aya fún Eri, àkọ́bí rẹ̀, orúkọ aya náà ni Tamari.
7
Ṣùgbọ́n Eri àkọ́bí Juda ṣe ènìyàn búburú níwájú Olúwa, Ọlọ́run sì pa á.
8
Nígbà náà ni Juda wí fún Onani, “Bá aya arákùnrin rẹ lòpọ̀, kí o ṣe ojúṣe rẹ fun un gẹ́gẹ́ bí àbúrò ọkọ, kí ó ba à le bí ọmọ fún un ní orúkọ arákùnrin rẹ.”
9
Ṣùgbọ́n Onani mọ̀ pé àwọn ọmọ náà kì yóò jẹ́ ti òun, nítorí náà ni gbogbo ìgbà tí ó bá wọlé tọ aya arákùnrin rẹ̀ lọ, ilẹ̀ ni ó ń da nǹkan ọkùnrin rẹ̀ sí, kí ó má bá a bímọ fún arákùnrin rẹ̀.
10
Ohun tí ó ń ṣe yìí burú lójú Olúwa, ó sì pa òun náà pẹ̀lú.
11
Nígbà náà ni Juda wí fún Tamari, ìyàwó ọmọ rẹ̀ pé, “Lọ máa gbé bí opó ní ilé baba rẹ, títí tí Ṣela yóò fi dàgbà ó lérò pé òun náà lè kú bí àwọn arákùnrin rẹ̀ tókù.” Nígbà náà ni Tamari ń lọ gbé ilé baba rẹ̀.
Settings