Skip to content
Gẹnẹsisi 38:12-23

Gẹnẹsisi 38:12-23

12
Lẹ́yìn ìgbà pípẹ́, ìyàwó Juda, ọmọbìnrin Ṣua sì kú, nígbà tí ọjọ́ ọ̀fọ̀ Juda sì pé, ó gòkè lọ sí Timna, sí ọ̀dọ̀ àwọn tí ń bá a rẹ́run àgùntàn rẹ̀, Hira ará Adullamu tí í ṣe ọ̀rẹ́ rẹ̀ sì bá a lọ.
13
Nígbà tí ẹnìkan sọ fún Tamari pé, “Baba ọkọ ọ̀ rẹ̀ wà ní ọ̀nà àjò rẹ̀ sí Timna láti rẹ́run àgùntàn rẹ̀.”
14
Ó bọ́ aṣọ opó rẹ̀, ó sì fi ìbòjú bo ojú ara rẹ̀ kí wọn má ba à mọ̀ ọ́n. Ó sì jókòó sí ẹnu-bodè Enaimu, èyí tí ó wà ní ọ̀nà Timna. Nítorí ó rí i wí pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ṣela ti dàgbà, síbẹ̀, a kò fi òun fún un gẹ́gẹ́ bí aya.
15
Nígbà tí Juda rí i, ó rò pé panṣágà ni, nítorí ó ti bo ojú rẹ̀.
16
Láìmọ̀ pé, aya ọmọ òun ní í ṣe, ó yà tọ̀ ọ́ ní ẹ̀bá ọ̀nà, ó wí pé, “Wá kí èmi kí ó lè wọlé tọ̀ ọ́.” Òun sì wí pé, “Kín ni ìwọ yóò fi fún mi kí ìwọ kó lè wọlé tọ̀ mí.”
17
Ó sì wí pé, “Èmi yóò fi ọmọ ewúrẹ́ kan ránṣẹ́ sí ọ láti inú agbo ẹran.” Obìnrin náà sì dáhùn pé, “Ṣé ìwọ yóò fún mi ní ohun kan gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí títí tí ìwọ yóò fi fi ránṣẹ́?”
18
Juda sì bi í pé, “Ẹ̀rí wo ni kí n fún ọ?” Ó sì dáhùn pé, “Èdìdì ìdámọ̀ okùn àti ọ̀pá ìtìlẹ̀ rẹ ti ń bẹ ní ọwọ́ rẹ.” Ó sì kó wọn fún un, ó sì sùn tì í, obìnrin náà sì lóyún nípasẹ̀ rẹ̀.
19
Lẹ́yìn ìgbà tí ó lọ, ó bọ́ ìbòjú ojú rẹ̀, ó sì tún wọ aṣọ opó rẹ̀ padà.
20
Juda sì rán ọmọ ewúrẹ́ náà láti ọwọ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀, ará Adullamu náà lọ láti gba ògo n nì wá lọ́wọ́ obìnrin náà. Ṣùgbọ́n wọn kò bá obìnrin náà níbẹ̀.
21
Ó béèrè lọ́wọ́ àwọn ènìyàn àdúgbò náà pé, “Níbo ni alágbèrè ojúbọ òrìṣà tí ó wà ní etí ọ̀nà Enaimu wà?” Wọ́n sì dá a lóhùn pé, “Kò sí alágbèrè ojúbọ òrìṣà kankan níbí.”
22
Ó sì padà lọ sọ́dọ̀ Juda ó wí fún un pé, “Èmí kò rí i, à ti pé àwọn aládùúgbò ibẹ̀ sọ pé kò sí alágbèrè ojúbọ òrìṣà kankan níbẹ̀.”
23
Nígbà náà ni Juda wí pé, “Jẹ́ kí ó máa kó àwọn ohun tí ó wà lọ́wọ́ rẹ̀ lọ bí kò ṣe bẹ́ẹ̀ a ó di ẹlẹ́yà. Mo sá à fi ọmọ ewúrẹ́ ránṣẹ́ sí i, ṣùgbọ́n ìwọ kò rí òun.”
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options