Gẹnẹsisi 2:8-14
8
Olúwa Ọlọ́run sì gbin ọgbà kan sí Edeni ní ìhà ìlà-oòrùn, níbẹ̀ ni ó fi ọkùnrin náà tí ó ti dá sí.
9
Olúwa Ọlọ́run sì mú kí onírúurú igi hù jáde láti inú ilẹ̀, àwọn igi tí ó dùn ún wò lójú, tí ó sì dára fún oúnjẹ. Ní àárín ọgbà náà ni igi ìyè àti igi tí ń mú ènìyàn mọ rere àti búburú wà.
10
Odò kan sì ń ti Edeni sàn wá láti bu omi rin ọgbà náà, láti ibẹ̀ ni odò náà gbé ya sí ipa mẹ́rin.
11
Orúkọ èkínní ni Pisoni, òun ni ó sàn yí gbogbo ilẹ̀ Hafila ká, níbi tí wúrà gbé wà.
12
(Wúrà ilẹ̀ náà dára, òjìá àti òkúta óníkìsì oníyebíye wà níbẹ̀ pẹ̀lú).
13
Orúkọ odò kejì ni Gihoni, òun ni ó sàn yí gbogbo ilẹ̀ Kuṣi ká.
14
Orúkọ odò kẹta ni Tigirisi, òun ni ó sàn ní apá ìlà-oòrùn ilẹ̀ Asiria. Odò kẹrin ni Eufurate.
Settings