Gẹnẹsisi 11:14-26
14
Nígbà tí Ṣela pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún ni ó bí Eberi.
15
Ṣela sì wà láààyè fún ọdún mẹ́tàlénírinwó (403) lẹ́yìn tí ó bí Eberi tán, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.
16
Eberi sì jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n, ó sì bí Pelegi.
17
Eberi sì wà láààyè fún irinwó ọdún ó lé ọgbọ̀n (430) lẹ́yìn tí ó bí Pelegi, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.
18
Nígbà tí Pelegi pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún ni ó bí Reu.
19
Pelegi sì tún wà láààyè fún igba ọdún ó lé mẹ́sàn-án (209) lẹ́yìn tí ó bí Reu, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.
20
Nígbà tí Reu pé ọdún méjìlélọ́gbọ̀n ni ó bí Serugu.
21
Reu tún wà láààyè lẹ́yìn tí ó bí Serugu fún igba ọdún ó lé méje (207), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin mìíràn.
22
Nígbà tí Serugu pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún ni ó bí Nahori.
23
Serugu sì wà láààyè fún igba ọdún lẹ́yìn tí ó bí Nahori, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.
24
Nígbà tí Nahori pé ọmọ ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n, ó bí Tẹra.
25
Nahori sì wà láààyè fún ọdún mọ́kàn dín lọ́gọ́fà lẹ́yìn ìbí Tẹra, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.
26
Lẹ́yìn tí Tẹra pé ọmọ àádọ́rin ọdún ó bí Abramu, Nahori àti Harani.
Settings