Skip to content
Ìṣe àwọn Aposteli 7:26-35

Ìṣe àwọn Aposteli 7:26-35

26
Ní ọjọ́ kejì Mose yọ sí àwọn ọmọ Israẹli méjì bí wọ́n ti ń jà. Òun si fẹ́ parí ìjà fún wọn. Ó wí pé, ‘Ènìyàn mi, ará ni ẹ̀yin; èéṣe tí ẹ̀yin fi ń ṣe ohun tí kò tọ́ sí ara yín?’
27
“Ṣùgbọ́n ẹni tí ó fínràn sí ẹnìkejì rẹ̀ ti Mose sí ẹ̀gbẹ́ kan, ó wí pé, ‘Ta ni ó fi ọ́ jẹ olórí àti onídàájọ́ lórí wa?
28
Ṣé ìwọ fẹ́ pa mí bí o ti pa ará Ejibiti lánàá?’
29
Mose sì sá nítorí ọ̀rọ̀ yìí, ó sì wa ṣe àtìpó ni ilẹ̀ Midiani, níbi tí ó gbé bí ọmọ méjì.
30
“Nígbà tí ogójì ọdún sì pé, angẹli Olúwa fi ara han Mose ní ijù, ní òkè Sinai, nínú ọ̀wọ́-iná nínú igbó.
31
Nígbà tí Mose sì rí i, ẹnu yà á sí ìran náà; nígbà tí ó sì súnmọ́ ọn láti wò ó fín, ohùn Olúwa kọ sí i,
32
wí pé ‘Èmi ni Ọlọ́run àwọn baba rẹ, Ọlọ́run Abrahamu, Ọlọ́run Isaaki, àti Ọlọ́run Jakọbu,’ Mose sì wárìrì pẹ̀lú ìbẹ̀rù, kò sì dáṣà láti wò ó mọ́.
33
“Olúwa sì wí fún un pé, ‘Bọ́ bàtà rẹ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ, nítorí ibi tí ìwọ dúró sí i nì ilẹ̀ mímọ́ ni.
34
Ní rí rí, mo ti rí ìpọ́njú àwọn ènìyàn mi tí ń bẹ ni Ejibiti, mo sì ti gbọ́ ìkérora wọn, mo sì sọ̀kalẹ̀ wá láti gbà wọ́n. Wá nísinsin yìí, Èmi ó sì rán ọ lọ sí ilẹ̀ Ejibiti.’
35
“Mose náà yìí tí wọ́n kọ̀, wí pé, ‘Ta ni ó fi jẹ olórí àti onídàájọ́?’ Òun náà ni Ọlọ́run rán lọ láti ọwọ́ angẹli, tí ó farahàn án ní pápá, láti ṣe olórí àti olùdáǹdè.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options