Ìṣe àwọn Aposteli 7:17-29
17
“Nígbà tí àkókò tí Ọlọ́run yóò mú ìlérí tí ó ṣe fún Abrahamu ṣẹ kù sí dẹ̀dẹ̀, àwọn ènìyàn wa ń gbèrú si gidigidi ní iye ní ilẹ̀ Ejibiti.
18
Ṣùgbọ́n ọba tuntun mìíràn tí kò mọ Josẹfu jẹ ní ilẹ̀ Ejibiti.
19
Òun náà ni ó ṣe àrékérekè sí àwọn ìbátan wa. Wọn sì hùwà búburú sí àwọn baba wa, tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi já àwọn ọmọ ọwọ́ wọn kúrò lọ́wọ́ wọn nítorí kí wọn má ṣe yè.
20
“Ní àkókò náà ni a bí Mose ọmọ tí ó se iyebíye, tí wọn sí bọ́ lóṣù mẹ́ta ni ilé baba rẹ̀.
21
Nígbà tí wọn sí gbe é sọnù, ọmọbìnrin Farao gbé e, ó sì tọ ọ́ dàgbà gẹ́gẹ́ bí ọmọ ara rẹ̀.
22
A sì kọ́ Mose ni gbogbo ọgbọ́n ara Ejibiti, ó sì pọ̀ ni ọ̀rọ̀ àti ní ìṣe.
23
“Nígbà tí Mose di ọmọ ogójì ọdún, ó sọ sí i lọ́kàn láti lọ bẹ àwọn ọmọ Israẹli ará rẹ̀ wò.
24
Nígbà tí ó sì rí ọ̀kan nínú wọ́n tí ará Ejibiti kan ń jẹ́ ní ìyà, ó gbèjà rẹ̀, ó gbẹ̀san ẹni tí wọ́n jẹ ní ìyà nípa lílu ará Ejibiti náà pa.
25
Mose rò bí àwọn ará òun mọ̀ pé Ọlọ́run yóò ti ọwọ́ òun gbà wọn; ṣùgbọ́n wọn kò mọ̀.
26
Ní ọjọ́ kejì Mose yọ sí àwọn ọmọ Israẹli méjì bí wọ́n ti ń jà. Òun si fẹ́ parí ìjà fún wọn. Ó wí pé, ‘Ènìyàn mi, ará ni ẹ̀yin; èéṣe tí ẹ̀yin fi ń ṣe ohun tí kò tọ́ sí ara yín?’
27
“Ṣùgbọ́n ẹni tí ó fínràn sí ẹnìkejì rẹ̀ ti Mose sí ẹ̀gbẹ́ kan, ó wí pé, ‘Ta ni ó fi ọ́ jẹ olórí àti onídàájọ́ lórí wa?
28
Ṣé ìwọ fẹ́ pa mí bí o ti pa ará Ejibiti lánàá?’
29
Mose sì sá nítorí ọ̀rọ̀ yìí, ó sì wa ṣe àtìpó ni ilẹ̀ Midiani, níbi tí ó gbé bí ọmọ méjì.
Settings