Skip to content
Ìṣe àwọn Aposteli 23:1-10

Ìṣe àwọn Aposteli 23:1-10

1
Paulu tẹjúmọ́ ìgbìmọ̀, ó sì wí pé, “Ẹ̀yin arákùnrin mi, èmi tí ń fi gbogbo ẹ̀rí ọkàn rere lo ayé mi níwájú Ọlọ́run títí fi di òní yìí.”
2
Nígbà yìí ni Anania olórí àlùfáà pàṣẹ fún àwọn tí ó dúró tí Paulu pé, kí wọn ó gbá a lẹ́nu.
3
Nígbà náà ni Paulu wí fún un pé, “Ọlọ́run yóò lù ọ́, ìwọ ògiri tí a kùn lẹ́fun: ìwọ jókòó láti dá mi lẹ́jọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin, ṣùgbọ́n ìwọ gan an rú òfin nípa pípàṣẹ pé kí a lù mí!”
4
Àwọn tí ó dúró tì Paulu sì wí pé, “Ìwọ́ ń gan olórí àlùfáà Ọlọ́run?”
5
Paulu sì dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin arákùnrin mi, èmi kò mọ̀ pé olórí àlùfáà ni: nítorí a tí kọ ọ́ pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ sọ̀rọ̀ olórí àwọn ènìyàn rẹ̀ ní búburú.’ ”
6
Ṣùgbọ́n nígbà tí Paulu ṣàkíyèsí pé, apá kan wọn jẹ́ Sadusi, apá kan sì jẹ́ Farisi, ó kígbe ní ìgbìmọ̀ pé, “Ẹ̀yin arákùnrin mi, èmi jẹ́ Farisi, ọmọ Farisi sì ni èmi. Mo dúró ní ìdájọ́ nítorí ìrètí mi nínú àjíǹde òkú.”
7
Nígbà tí ó sì tí wí èyí, ìyapa dé láàrín àwọn Farisi àti àwọn Sadusi: àjọ sì pín sì méjì.
8
Nítorí tí àwọn Sadusi wí pé, kò sì àjíǹde, tàbí angẹli, tàbí ẹ̀mí: ṣùgbọ́n àwọn Farisi jẹ́wọ́ méjèèjì.
9
Ó sì di ariwo ńlá, nínú àwọn olùkọ́ òfin tí ó wà ni apá tí àwọn Farisi dìde, wọ́n ń jà, wí pé, “Àwa kò rí ohun búburú kan lára ọkùnrin yìí,” wọ́n wí “àwa kò sì mọ̀ nítòótọ́ bí angẹli kan tàbí ẹ̀mí kan ń ba à sọ̀rọ̀?”
10
Nígbà tí ìyapa sì di ńlá, tí olórí ogun bẹ̀rù kí Paulu má ba à di fífàya lọ́wọ́ wọn, ó pàṣẹ pé ki àwọn ọmọ-ogun sọ̀kalẹ̀ lọ láti fi ipá mú un kúrò láàrín wọn, kí wọn sì mú un wá sínú àgọ́ àwọn ológun.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Reading Width 45 chars

Options