2 Ọba 2:9-15
9
Nígbà tí wọ́n rékọjá, Elijah sì wí fún Eliṣa pé, “Sọ fún mi, kí ni èmi lè ṣe fún ọ kí ó tó di wí pé wọ́n gbà mí kúrò lọ́dọ̀ rẹ?” “Jẹ́ kí èmi kí ó jogún ìlọ́po méjì ẹ̀mí rẹ.” Ó dá a lóhùn.
10
“Ìwọ ti béèrè ohun tí ó ṣòro,” Elijah wí pé, “Síbẹ̀ tí ìwọ bá rí mi nígbà tí a bá gbà mí kúrò lọ́wọ́ rẹ, yóò jẹ́ tìrẹ bí bẹ́ẹ̀ kọ́ kò ní rí bẹ́ẹ̀.”
11
Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ń rìn lọ tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ pọ̀, lọ́gán kẹ̀kẹ́ iná àti ẹṣin iná yọ sí wọn ó sì ya àwọn méjèèjì nípa, Elijah sì gòkè lọ sí ọ̀run pẹ̀lú àjà.
12
Eliṣa rí èyí ó sì kígbe sókè, “Baba mi! Baba mi! Kẹ̀kẹ́ àti ẹlẹ́ṣin Israẹli!” Eliṣa kò sì rí i mọ́. Ó sì mú aṣọ ara rẹ̀ ó sì fà wọ́n ya sọ́tọ̀.
13
Ó sì mú agbádá tí ó ti jábọ́ láti ọ̀dọ̀ Elijah ó sì padà lọ, ó sì dúró lórí bèbè Jordani.
14
Ó sì mú agbádá náà tí ó jábọ́ láti ọwọ́ rẹ̀, ó sì lu omi pẹ̀lú rẹ̀. “Níbo ni Olúwa Ọlọ́run Elijah wà?” Ó béèrè. Nígbà tí ó lu omi náà, ó sì pín sí apá ọ̀tún àti sí òsì, Eliṣa sì rékọjá.
15
Àwọn ọmọ wòlíì láti Jeriko, tí wọ́n ń wò, wí pé, “Ẹ̀mí Elijah sinmi lé Eliṣa.” Wọ́n sì lọ láti lọ bá a, wọ́n sì dojúbolẹ̀ níwájú rẹ̀.
Settings