2 Kọrinti 2:5-11
5
Bí ẹnikẹ́ni bá fa ohun ìbànújẹ́ kì í ṣe èmi ni ó bà nínú jẹ́, bí kò ṣe ẹ̀yin fúnra yín, níwọ̀n ìyówù kí ó jẹ́; n kò fẹ́ sọ ọ́ lọ́nà líle jù.
6
Ìyà náà tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti fi jẹ́ irú ènìyàn bẹ́ẹ̀ tó fún un.
7
Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin ìbá kúkú dáríjì í, kí ẹ sí tù ú nínú ní gbogbo ọ̀nà, kí ìbànújẹ́ má bà á bo irú ènìyàn bẹ́ẹ̀ mọ́lẹ̀.
8
Nítorí náà mo bẹ̀ yín, ẹ fi ìdánilójú ìfẹ́ yín hàn sí irú ẹni náà.
9
Ìdí tí mo ṣe kọ̀wé ni kí èmi ba à lè rí ẹ̀rí dìímú nípa ìgbọ́ràn yín nínú ohun gbogbo.
10
Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá dáríjì ẹnikẹ́ni, èmi pẹ̀lú dáríjì í. Ohun tí èmi pẹ̀lú bá fi jì, nítorí tiyín ní mo fi jì níwájú Kristi.
11
Kí Satani má ba à rẹ́ wa jẹ. Nítorí àwa kò ṣe aláìmọ́ àrékérekè rẹ̀.
Settings