Skip to content
2 Kọrinti 2:1-4

2 Kọrinti 2:1-4

1
Nítorí náà mo tí pinnu nínú ara mí pé, èmi kì yóò tún fi ìbànújẹ́ tọ̀ yin wá.
2
Nítorí pé bí èmi bá mú inú yín bàjẹ́, ǹjẹ́ ta ni ẹni ti ìbá mú inú mí dùn ní àkókò tí inú mi bá bàjẹ́ bí kò ṣe ẹni tí mo ti ba nínú jẹ́?
3
Èmi sì kọ̀wé bí mo tí kọ sí yín pé, nígbà tí mo bá sì de, kí èmi má ṣe ni ìbànújẹ́ lọ́dọ̀ àwọn ti ìbá mú mi ní ayọ̀, nítorí tí mo ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú gbogbo yín, wí pé ẹ̀yin yóò jẹ́ alábápín ayọ̀ mi.
4
Nítorí pé nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ wàhálà àti ìrora ọkàn mí ni mo ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ omijé kọ̀wé sí yín; kì í ṣe nítorí kí a lè bà yín nínú jẹ́, ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin bá a lè mọ bí ìfẹ́ tí mo ní sí yín ṣe jinlẹ̀ tó.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options