Skip to content
2 Kọrinti 11:7-15

2 Kọrinti 11:7-15

7
Tàbí ẹ̀ṣẹ̀ ni mo dá bí èmi ti ń rẹ ara mí sílẹ̀ kí a lè gbé yín ga, nítorí tí mo wàásù ìyìnrere Ọlọ́run fún un yín lọ́fẹ̀ẹ́.
8
Èmí ń ja ìjọ mìíràn ni olè nípa gbígba ìpèsè owó ki èmi bà á lè sìn yín.
9
Nígbà tí mo sì wà pẹ̀lú yín, tí mo sì ṣe aláìní, èmi kò dẹ́rù pa ẹnikẹ́ni, nítorí ohun tí mo ṣe aláìní ni àwọn ará tí ó ti Makedonia wá ti mú wá. Bẹ́ẹ̀ ni nínú ohun gbogbo mo pa ara mi mọ́ láti má ṣe jẹ́ ẹrù fún yín, èmi yóò sì pa ara mi mọ́ bẹ́ẹ̀.
10
Ó jẹ́ òtítọ́, Kristi tí ń bẹ nínú mi pé kò sí ẹni tí ó lè dá mi lẹ́kun ìṣògo yìí ni gbogbo ẹkùn Akaia.
11
Nítorí kín ni? Nítorí èmi kò fẹ́ràn yín ni bí? Ọlọ́run mọ̀.
12
Èmi yóò tẹ̀síwájú láti máa ṣe ohun ti èmi ń ṣe láti le mú ìjákulẹ̀ bá àwọn tí wọn ń wá ọ̀nà láti bá wa dọ́gba nínú èyí ti àwa ń ṣògo lé lórí.
13
Nítorí irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ ni àwọn èké Aposteli àwọn ẹni ti ń ṣiṣẹ́ ẹ̀tàn, tí ń pa wọ́n dà di aposteli Kristi.
14
Kì í sì í ṣe ohun ìyanu; nítorí Satani, tìkára rẹ̀ ń pa ara rẹ̀ dàbí angẹli ìmọ́lẹ̀.
15
Nítorí náà kì í ṣe ohun ńlá bí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú bá pa ara wọn dàbí àwọn ìránṣẹ́ òdodo; ìgbẹ̀yìn àwọn ẹni tí yóò rí gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options