Skip to content
2 Kronika 23:12-20

2 Kronika 23:12-20

12
Nígbà tí Ataliah gbọ́ igbe àwọn ènìyàn tí wọ́n ń sáré tí wọ́n ń kígbe ọba, ó lọ sí ọ̀dọ̀ wọn ní ilé Olúwa.
13
Ó sì wò, sì kíyèsi, ọba dúró ní ibùdó rẹ̀ ní ẹ̀bá ẹnu-ọ̀nà, àti àwọn balógun àti àwọn afùnpè lọ́dọ̀ ọba, gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà sì yọ̀, wọ́n sì fọn ìpè, àti àwọn akọrin pẹ̀lú ohun èlò ìyìn. Nígbà náà ni Ataliah fa aṣọ rẹ̀ ya, ó sì kégbe wí pé, “Ọ̀tẹ̀! Ọ̀tẹ̀!”
14
Jehoiada àlùfáà mú àwọn alákòóso ọ̀rọ̀ọ̀rún, tí ó wà ní àbojútó àwọn ọ̀wọ́ ogun, ó sì wá wí fún wọn pé, “Mú un jáde wá láàrín àwọn ọgbà, kí a sì fi idà pa ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé.” Nítorí tí àlùfáà ti wí pé, “Má ṣe pa á nínú ilé Olúwa.”
15
Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n fi ipá mú un kí ó tó dé ẹnu-ọ̀nà àbáwọlé ẹṣin ti ilé ọba, wọ́n sì ti pa á níbẹ̀.
16
Nígbà náà ni Jehoiada, dá májẹ̀mú pé òun àti àwọn ènìyàn àti ọba yóò jẹ́ ènìyàn Olúwa.
17
Gbogbo àwọn ènìyàn lọ sí ilé Baali, wọ́n sì fà á ya lulẹ̀. Wọ́n fọ́ àwọn pẹpẹ àti àwọn òrìṣà, wọ́n sì pa Mattani àlùfáà Baali níwájú àwọn pẹpẹ.
18
Nígbà náà, Jehoiada tẹ àwòrán ilé Olúwa sí ọwọ́ àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ará Lefi ẹni tí Dafidi ti fi ṣe iṣẹ́ ní ilé Olúwa láti tẹ ẹbọ sísun ti Olúwa bí a ti kọ ọ́ nínú òfin Mose, pẹ̀lú ayọ̀ àti orin kíkọ, gẹ́gẹ́ bí Dafidi ti pàṣẹ.
19
Ó mú àwọn olùṣọ́nà wà ni ipò ìdúró ní ẹnu odi ilé Olúwa kí ẹni aláìmọ́ nínú ohunkóhun kó má ba à wọlé.
20
Ó mú pẹ̀lú rẹ̀ àwọn alákòóso ọ̀rọ̀ọ̀rún, àwọn ẹni ọlá, àwọn olórí àwọn ènìyàn àti gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà. Ó sì mú ọba sọ̀kalẹ̀ wá láti ilé Olúwa. Wọ́n lọ sínú ààfin láti ẹnu òde ti òkè. Wọ́n sì fi ọba jókòó lórí ìtẹ́.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options