1 Samuẹli 26:1-5
1
Nígbà náà ni àwọn ará Sifi tọ Saulu wá sí Gibeah, wọn wí pé, “Dafidi kò ha fi ara rẹ̀ pamọ́ níbi òkè Hakila, èyí tí ó wà níwájú Jeṣimoni?”
2
Saulu sì dìde ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ijù Sifi ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) àṣàyàn ènìyàn ni Israẹli sì pẹ̀lú rẹ̀ láti wá Dafidi ni ijù Sifi.
3
Saulu sì pàgọ́ rẹ̀ ní ibi òkè Hakila tí o wà níwájú Jeṣimoni lójú ọ̀nà, Dafidi sì jókòó ni ibi ijù náà, ó sì rí pé Saulu ń tẹ̀lé òun ni ijù náà.
4
Dafidi sì rán ayọ́lẹ̀wò jáde, ó sì mọ nítòótọ́ pé Saulu ń bọ̀.
5
Dafidi sì dìde, ó sì wá sí ibi ti Saulu pàgọ́ sí: Dafidi rí ibi tí Saulu gbé dùbúlẹ̀ sí, àti Abneri ọmọ Neri, olórí ogun rẹ̀: Saulu sì dùbúlẹ̀ láàrín àwọn kẹ̀kẹ́, àwọn ènìyàn náà sì pàgọ́ wọn yí i ká.
Settings