1 Peteru 5:1-9
1
Àwọn alàgbà tí ń bẹ láàrín yín ni mo gbànímọ̀ràn, èmi ẹni tí ń ṣe alàgbà bí ẹ̀yin, àti ẹlẹ́rìí ìyà Kristi, àti alábápín nínú ògo tí a ó fihàn.
2
Ẹ máa tọ́jú agbo Ọlọ́run tí ń bẹ láàrín yín, ẹ máa bojútó o, kì í ṣe àfipáṣe, bí kò ṣe tìfẹ́tìfẹ́; kó má sì jẹ́ fún èrè ìjẹkújẹ, bí kò ṣe pẹ̀lú ìpinnu tí ó múra tan.
3
Bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe bí ẹni tí ń lo agbára lórí ìjọ, ṣùgbọ́n kí ẹ ṣe ara yín ní àpẹẹrẹ fún agbo.
4
Nígbà tí Olórí Olùṣọ́-àgùntàn bá sì fi ara hàn, ẹ̀yin ó gba adé ògo ti kì í sá.
5
Bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú, ẹ̀yin ọ̀dọ́, ẹ tẹríba fún àwọn alàgbà. Àní, gbogbo yín ẹ máa tẹríba fún ara yín kí ẹ fi ìrẹ̀lẹ̀ wọ ara yín ní aṣọ: nítorí, “Ọlọ́run kọ ojú ìjà sí àwọn agbéraga, ṣùgbọ́n ó ń fi oore-ọ̀fẹ́ fún àwọn onírẹ̀lẹ̀.”
6
Nítorí náà, ẹ rẹ ara yin sílẹ̀ lábẹ́ ọwọ́ agbára Ọlọ́run, kí òun lè gbe yín ga lákokò.
7
Ẹ máa kó gbogbo àníyàn yín lé e; nítorí tí òun ń ṣe ìtọ́jú yín.
8
Ẹ máa wà ni àìrékọjá, ẹ máa ṣọ́ra; nítorí èṣù ọ̀tá yín, bí i kìnnìún tí ń ké ramúramù, ó ń rìn káàkiri, ó ń wa ẹni tí yóò pajẹ.
9
Ẹ kọ ojú ìjà sí i pẹ̀lú ìdúró ṣinṣin nínú ìgbàgbọ́, bí ẹ̀yin ti mọ̀ pé ìyà kan náà ni àwọn ará yín tí ń bẹ nínú ayé ń jẹ.
Settings