1 Ọba 9:1-6
1
Nígbà tí Solomoni sì parí kíkọ́ ilé Olúwa àti ààfin ọba, tí ó sì ti ṣe gbogbo nǹkan tí ó ń fẹ́ láti ṣe,
2
Olúwa sì farahàn Solomoni ní ìgbà kejì, bí ó ti farahàn án ní Gibeoni.
3
Olúwa sì wí fún un pé, “Èmi ti gbọ́ àdúrà rẹ àti ẹ̀bẹ̀ rẹ tí ìwọ ti bẹ̀ níwájú mi, mo ti ya ilé yìí sí mímọ́, tí ìwọ ti kọ́, nípa fífi orúkọ mi síbẹ̀ títí láé. Ojú mi àti ọkàn mi yóò wà níbẹ̀ nígbà gbogbo.
4
“Bí ìwọ bá rìn níwájú mi ní ọkàn òtítọ́ àti ìdúró ṣinṣin, bí i Dafidi baba rẹ ti rìn, kí o sì ṣe gbogbo èyí tí mo ti paláṣẹ fún ọ àti kí o sì pa àṣẹ mi àti òfin mi mọ́,
5
Èmi yóò fi ìdí ìtẹ́ ìjọba rẹ múlẹ̀ lórí Israẹli títí láé, bí mo ti ṣe ìlérí fún Dafidi baba rẹ nígbà tí mo wí pé, ‘Ìwọ kì yóò kùnà láti ní ọkùnrin kan lórí ìtẹ́ Israẹli.’
6
“Ṣùgbọ́n tí ìwọ tàbí àwọn ọmọ rẹ bá yípadà kúrò lọ́dọ̀ mi, tí ẹ kò sì pa òfin mi mọ́ àti àṣẹ mi tí mo ti fi fún ọ, tí ẹ sì lọ láti sin ọlọ́run mìíràn, tí ẹ sì ń sìn wọ́n,
Settings