Skip to content
1 Ọba 16:17-24

1 Ọba 16:17-24

17
Nígbà náà ni Omri àti gbogbo Israẹli pẹ̀lú rẹ̀ kúrò ní Gibetoni, wọ́n sì dó ti Tirsa.
18
Nígbà tí Simri sì ri pé a ti gba ìlú, ó sì wọ inú ààfin ilé ọba lọ, ó sì tẹ iná bọ ilé ọba lórí ara rẹ̀, ó sì kú,
19
nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tí ó ti ṣẹ̀, ní ṣíṣe búburú níwájú Olúwa àti ní rírìn ní ọ̀nà Jeroboamu àti nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tí ó ti ṣe àti tí ó ti mú Israẹli ṣẹ̀.
20
Ní ti ìyókù ìṣe Simri, àti ọ̀tẹ̀ rẹ̀ tí ó dì, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ọ̀rọ̀ ọjọ́ àwọn ọba Israẹli?
21
Nígbà náà ní àwọn ènìyàn Israẹli dá sí méjì; apá kan wọn ń tọ Tibni ọmọ Ginati lẹ́yìn, láti fi í jẹ ọba, apá kan tókù sì ń tọ Omri lẹ́yìn.
22
Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn tí ń tọ Omri lẹ́yìn borí àwọn tí ń tọ Tibni ọmọ Ginati lẹ́yìn. Bẹ́ẹ̀ ni Tibni kú, Omri sì jẹ ọba.
23
Ní ọdún kọkànlélọ́gbọ̀n Asa ọba Juda, Omri bẹ̀rẹ̀ sí ń jẹ ọba lórí Israẹli, ó sì jẹ ọba ní ọdún méjìlá, ọdún mẹ́fà ní Tirsa.
24
Ó sì ra òkè Samaria lọ́wọ́ Ṣemeri ní tálẹ́ǹtì méjì fàdákà, ó sì kọ́ ìlú sórí rẹ̀, ó sì pe ìlú náà ní Samaria, nípa orúkọ Ṣemeri, orúkọ ẹni tí ó kọ́kọ́ ni òkè náà.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options