Skip to content
1 Kọrinti 6:1-11

1 Kọrinti 6:1-11

1
Bí ẹnikẹ́ni nínú yín bá ni èdè-àìyedè sí ẹnìkejì rẹ̀, ó ha gbọdọ̀ lọ pè é lẹ́jọ́ níwájú àwọn aláìṣòótọ́ bí, bí kò ṣe níwájú àwọn ènìyàn mímọ́?
2
Ṣé ẹ̀yin kò mọ̀ pé àwọn ẹni mímọ́ ni yóò ṣe ìdájọ́ ayé? Ǹjẹ́ bí ó ba ṣe ìpàṣẹ yín ni a o ti ṣe ìdájọ́ ayé, kín ni ìdí tí ẹ kò fi yanjú àwọn ọ̀rọ̀ kéékèèké wọ̀nyí láàrín ara yín.
3
Ẹ kò mọ̀ pé àwa ni a ó ṣe ìdájọ́ àwọn angẹli ní? Mélòó mélòó àwọn nǹkan tó wà nínú ayé yìí.
4
Nítorí náà, bí ẹ̀yin bá ni aáwọ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí, ǹjẹ́ ẹ ó yàn láti gba ìdájọ́ lọ́dọ̀ àwọn tí ìgbé ayé wọn ń di gígàn nínú ìjọ.
5
Mo sọ èyí kí ojú lè tì yín. Ṣé ó ṣe é ṣe kí a máa rín ẹnìkan láàrín yín tí ó gbọ́n níwọ̀n láti ṣe ìdájọ́ èdè-àìyedè láàrín àwọn onígbàgbọ́?
6
Ṣùgbọ́n dípò èyí, arákùnrin kan ń pe arákùnrin kejì lẹ́jọ́ sí ilé ẹjọ́ níwájú àwọn aláìgbàgbọ́.
7
Ǹjẹ́ nísinsin yìí, àbùkù ni fún un yín pátápátá pé ẹ̀yin ń bá ara yín ṣe ẹjọ́. Kín ní ṣe tí ẹ kò kúkú gba ìyà? Kín ló dé tí ẹ kò kúkú gba ìrẹ́jẹ kí ẹ sì fi i sílẹ̀ bẹ́ẹ̀?
8
Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ń jẹ ni ní ìyà, ẹ sì ń rẹ́ ni jẹ. Ẹ̀yin si ń ṣe èyí sí àwọn arákùnrin yín.
9
Ẹ̀yin kò mọ̀ pé àwọn aláìṣòótọ́ kì í yóò jogún ìjọba Ọlọ́run? Kí a máa tàn yín jẹ; kì í ṣe àwọn àgbèrè, tàbí àwọn abọ̀rìṣà, tàbí àwọn panṣágà, tàbí àwọn ọkùnrin tí ń ṣe ìṣe obìnrin tàbí àwọn ọkùnrin tí ń ba ara wọn lòpọ̀
10
tàbí àwọn olè, tàbí àwọn wọ̀bìà, tàbí àwọn ọ̀mùtí, tàbí àwọn apẹ̀gàn, tàbí àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà ni yóò jogún ìjọba Ọlọ́run.
11
Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlòmíràn nínú yín sì tí jẹ́ rí; ṣùgbọ́n a ti sọ yín di mímọ́, ṣùgbọ́n a ti dá yín láre ni orúkọ Jesu Kristi Olúwa, àti nípa Ẹ̀mí Mímọ́ Ọlọ́run wa.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Options