1 Kronika 9:1-22
1
Gbogbo Israẹli ni a kọ lẹ́sẹẹsẹ nínú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ àwọn baba ńlá nínú ìwé àwọn ọba Israẹli. Àwọn ènìyàn Juda ni a kó ní ìgbèkùn lọ sí Babeli nítorí àìṣòótọ́ wọn.
2
Nísinsin yìí, àwọn tí ó kọ́kọ́ tún tẹ̀dó lórí ohun ìní wọn ní ìlú wọn ni díẹ̀ nínú àwọn ọmọ Israẹli, àwọn àlùfáà, àwọn ará Lefi àti àwọn ìránṣẹ́ ilé Olúwa.
3
Àwọn tí ó wá láti Juda láti Benjamini àti láti Efraimu àti Manase tí ó ń gbé ní Jerusalẹmu jẹ́:
4
Uttai ọmọ Ammihudu, ọmọ Omri, ọmọ Imri, ọmọ Bani, ìran ọmọ Peresi ọmọ Juda.
5
Àti nínú ará Ṣilo: Asaiah àkọ́bí àti àwọn ọmọ rẹ̀.
6
Ní ti ará Sera: Jeueli. Àwọn ènìyàn láti Juda sì jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin ó dín mẹ́wàá (690).
7
Àti nínú àwọn ọmọ Benjamini ni: Sallu ọmọ Meṣullamu, ọmọ Hodafiah; ọmọ Hasenuah;
8
Ibinaiah ọmọ Jerohamu; Ela ọmọ Ussi, ọmọ Mikri; àti Meṣullamu ọmọ Ṣefatia; ọmọ Reueli, ọmọ Ibinijah.
9
Àwọn ènìyàn láti Benjamini gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe kọ ọ́ nínú ìran wọn nínú ìtàn ìdílé láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn, tí ó jẹ́ ẹgbẹ̀rún ó dín mẹ́rìnlélógójì (956). Gbogbo àwọn ọkùnrin yí jẹ́ àwọn olórí àwọn ìdílé.
10
Ní ti àwọn àlùfáà: Jedaiah; Jehoiaribi; Jakini;
11
Asariah ọmọ Hilkiah, ọmọ Meṣullamu, ọmọ Sadoku, ọmọ Meraioti, ọmọ Ahitubu, olórí tí ó ń bojútó ilé Ọlọ́run;
12
Adaiah ọmọ Jerohamu, ọmọ Paṣuri, ọmọ Malkiah; àti Masai ọmọ Adieli, ọmọ Jahisera, ọmọ Meṣullamu ọmọ Meṣilemiti, ọmọ Immeri.
13
Àwọn àlùfáà, tí wọ́n jẹ́ àwọn olórí àwọn ìdílé, tí ó jẹ́ ẹgbẹ̀sán ó dín méjì (1,760). Wọ́n jẹ́ alágbára ọkùnrin, tí wọ́n lè dúró fún iṣẹ́ ìránṣẹ́ nínú ilé Ọlọ́run.
14
Ní ti àwọn ará Lefi: Ṣemaiah ọmọ Haṣubu, ọmọ Asrikamu, ọmọ Haṣabiah ará Merari;
15
Bakibakari, Hereṣi, Galali àti Mattaniah, ọmọ Mika, ọmọ Sikri, ọmọ Asafu;
16
Obadiah ọmọ Ṣemaiah, ọmọ Galali, ọmọ Jedutuni; àti Berekiah ọmọ Asa, ọmọ Elkana, tí ó ń gbé nínú àwọn ìlú àwọn ará Netofa.
17
Àwọn olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà: Ṣallumu, Akkubu, Talmoni, Ahimani àti arákùnrin wọn, Ṣalumu olóyè wọn,
18
ti wà ní ipò ìdúró ní ẹnu-ọ̀nà ọba ní apá ìhà ìlà-oòrùn títí di àkókò yí. Wọ̀nyí ni àwọn olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà tí ó jẹ́ ti ìpàgọ́ àwọn ará Lefi.
19
Ṣallumu ọmọ Kore ọmọ Ebiasafi, ọmọ Kora, àti àwọn olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà ẹlẹgbẹ́ rẹ̀. Láti ìdílé rẹ̀ (àwọn ará Korati) ni ó dúró fún ṣíṣọ́ ìloro ẹnu-ọ̀nà àgọ́ gẹ́gẹ́ bí baba wọn ti ń dúró fún ṣíṣọ́ àbáwọlé ibùgbé Olúwa.
20
Ní ìgbà àkọ́kọ́ Finehasi ọmọ Eleasari jẹ́ olórí fún àwọn olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà, Olúwa sì wà pẹ̀lú rẹ̀.
21
Sekariah, ọmọ Meṣelemiah jẹ́ olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà ní àbáwọlé sí àgọ́ ibi ìpàdé.
22
Gbogbo rẹ̀ lápapọ̀, àwọn tí a yàn láti jẹ́ olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà ní àwọn ìloro jẹ́ igba ó lé méjìlá (212). A ka àwọn wọ̀nyí nípa ìdílé ní ìletò wọn. Àwọn olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà ni a ti yàn sí ipò láti ọ̀dọ̀ Dafidi àti Samuẹli, aríran, nítorí òtítọ́ wọn.
Settings