1 Kronika 8:29-38
29
Jeieli, baba Gibeoni ń gbé ní Gibeoni. Ìyàwó o rẹ̀ a má jẹ́ Maaka,
30
àkọ́bí rẹ̀ a sì máa jẹ́ Abdoni wọ̀nyí sì ń tẹ̀lé Suri, Kiṣi, Baali, Neri, Nadabu,
31
Gedori Ahio, Sekeri
32
pẹ̀lú Mikiloti, tí ó jẹ́ baba Ṣimea. Wọ́n ń gbé ní ẹ̀bá ìbátan wọn ní Jerusalẹmu.
33
Neri jẹ́ baba Kiṣi, Kiṣi baba Saulu àti Saulu baba Jonatani, Malikiṣua, Abinadabu àti Eṣi-Baali.
34
Ọmọ Jonatani: Meribu-Baali tí ó jẹ́ baba Mika.
35
Àwọn ọmọ Mika: Pitoni, Meleki, Tarea, àti Ahasi.
36
Ahasi jẹ́ baba a Jeheada, Jeheada jẹ́ baba a Alemeti, Asmafeti àti Simri, Simri sì jẹ́ baba Mosa.
37
Mosa jẹ́ baba Binea; Rafa sì jẹ́ ọmọ rẹ̀, Eleasa ọmọ rẹ̀ àti Aseli ọmọ rẹ̀.
38
Aseli ní ọmọ mẹ́fà pẹ̀lú wọ̀nyí ni orúkọ wọn: Asrikamu, Bokeru, Iṣmaeli, Ṣeariah, Obadiah àti Hanani. Gbogbo wọ̀nyí ni ọmọ Aseli.
Settings