1 Kronika 4:1-15
1
Àwọn ọmọ Juda: Peresi, Hesroni, Karmi, Huri àti Ṣobali.
2
Reaiah ọmọ Ṣobali ni baba Jahati, àti Jahati baba Ahumai àti Lahadi. Àwọn wọ̀nyí ni ẹ̀yà ará Sorati.
3
Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Etamu: Jesreeli, Iṣima, Idbaṣi, orúkọ arábìnrin wọn sì ni Haseleponi
4
Penueli sì ni baba Gedori, àti Eseri baba Huṣa. Àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Huri, àkọ́bí Efrata àti baba Bẹtilẹhẹmu.
5
Aṣihuri baba Tekoa sì ní aya méjì, Hela àti Naara.
6
Naara sì bí Ahussamu, Heferi Temeni àti Haaṣtari. Àwọn wọ̀nyí sì ni àwọn ọmọ Naara.
7
Àwọn ọmọ Hela: Sereti Sohari, Etani,
8
àti Kosi ẹni tí ó jẹ́ baba Anubu àti Sobeba àti ti àwọn ẹ̀yà Aharheli ọmọ Harumu.
9
Jabesi sì ní ọlá ju àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin lọ. Ìyá rẹ̀ sì sọ ọ́ ní Jabesi wí pé, “Mo bí i nínú ìpọ́njú.”
10
Jabesi sì kígbe sókè sí Ọlọ́run Israẹli wí pé, “Háà, Ìwọ yóò bùkún fún mi, ìwọ yóò sì mú agbègbè mi tóbi! Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ kí ó wà pẹ̀lú mi kí o sì pa mi mọ́ kúrò nínú ibi; kí èmi kí ó le ní ìdáǹdè kúrò nínú ìrora.” Ọlọ́run sì gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ rẹ̀.
11
Kelubu arákùnrin Ṣuha, sì jẹ́ baba Mehiri, ẹni tí ó jẹ́ baba Eṣtoni.
12
Eṣtoni sì jẹ́ baba Beti-Rafa, Pasea àti Tehina ti baba ìlú Nahaṣi. Àwọn wọ̀nyí ni ọkùnrin Reka.
13
Àwọn ọmọ Kenasi: Otnieli àti Seraiah. Àwọn ọmọ Otnieli: Hatati àti Meonotai.
14
Meonotai sì ni baba Ofira. Seraiah sì jẹ́ baba Joabu, baba Geharaṣinu. A pè báyìí nítorí àwọn ènìyàn àwọn oníṣọ̀nà ní ìwọ̀n.
15
Àwọn ọmọ Kalebu ọmọ Jefunne: Iru, Ela, àti Naamu. Àwọn ọmọ Ela: Kenasi.
Settings