Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Tychicus

7 ẹsẹ · 5 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. Sopateru ará Berea ọmọ Pirusi sì bá a lọ dé Asia, àti nínú àwọn ará Tẹsalonika, Aristarku àti Sekundu, àti Gaiusi ará Dabe, àti Timotiu; Tikiku àti Tirofimu ará Asia.

  2. Tikiku, arákùnrin olùfẹ́ àti ìránṣẹ́ olóòtítọ́ nínú Olúwa yóò sọ ohun gbogbo dí mí mọ̀ fún yín, kí ẹ̀yin pẹ̀lú lè mọ̀ bí nǹkan ti rí fún mí àti bí mo tí ń ṣe sí.

  3. Ẹni tí mo rán sí yín nítorí èyí náà, kí ẹ lè mọ̀ bí a tí wà, kì òun lè tu ọkàn yín nínú.

  4. Gbogbo bí nǹkan ti rí fún mi ní Tikiku yóò jẹ́ kí ẹ mọ̀. Òun jẹ́ arákùnrin olùfẹ́ àti olóòtítọ́ ìránṣẹ́ àti ẹlẹgbẹ́ nínú Olúwa,

  5. ẹni tí èmí ń rán sí yín nítorí èyí kan náà, kí ẹ̀yin lè mọ́ bí a ti wà, kí òun kí ó lè tu ọkàn yín nínú.

  6. Mo rán Tikiku ní iṣẹ́ lọ sí Efesu.

  7. Ní kété tí mo bá ti rán Artema tàbí Tikiku sí ọ, sa gbogbo ipá rẹ láti tọ̀ mí wá ní Nikopoli, nítorí mo ti pinnu láti lo ìgbà òtútù mi níbẹ̀.