Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Trial: Before court
Àwọn ẹsẹ nípa Before court
Ọmọkùnrin kan wà tí ìyá rẹ̀ jẹ́ ọmọ Israẹli baba rẹ̀ sì jẹ́ ará Ejibiti. Ó jáde lọ láàrín àwọn ọmọ Israẹli, ìjà sì ṣẹlẹ̀ nínú àgọ́ láàrín òun àti ọmọ Israẹli kan.
Ọmọkùnrin arábìnrin Israẹli náà sọ̀rọ̀-òdì sí orúkọ Olúwa pẹ̀lú èpè, wọ́n sì mú un tọ Mose wá. (Orúkọ ìyá rẹ̀ ní Ṣelomiti, ọmọbìnrin Debiri, ti ẹ̀yà Dani.)
Wọ́n fi í sínú túbú kí Olúwa to sọ ohun tí wọn yóò ṣe fún wọn.
Olúwa sì sọ fún Mose pé,
“Mú asọ̀rọ̀-òdì náà jáde wá sẹ́yìn àgọ́, kí gbogbo àwọn tí ó gbọ́ pé ó ṣépè gbé ọwọ́ wọn lórí ọkùnrin náà láti fihàn pé ó jẹ̀bi. Lẹ́yìn náà ni kí gbogbo àpéjọpọ̀, sọ ọ́ ní òkúta pa.