Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Tower: Of Hananeel

4 ẹsẹ · 16 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Of Hananeel

  1. Eliaṣibu olórí àlùfáà àti àwọn àlùfáà arákùnrin rẹ̀ lọ ṣiṣẹ́, wọ́n sì tún ibodè Àgùntàn mọ. Wọ́n yà á sí mímọ́, wọ́n sì gbé ìlẹ̀kùn dúró sí ibi tí ó yẹ, wọ́n mọ ọ́n títí dé ilé ìṣọ́ ọgọ́rùn-ún, èyí tí wọ́n yà sí mímọ́ títí dé ilé ìṣọ́ gíga Hananeli.

  2. kọjá ẹnu ibodè Efraimu ibodè Jeṣana, ẹnu ibodè ẹja, ilé ìṣọ́ Hananeli àti ilé ìṣọ́ ọgọ́rùn-ún, títí dé ẹnu ibodè àgùntàn. Wọ́n sì dúró ní ibodè ìṣọ́.

  3. “Ọjọ́ náà ń bọ̀,” ni Olúwa wí, “tí wọn yóò tún ìlú yìí kọ́ fún mi láti ilé ìṣọ́ Hananeli dé igun ẹnu ibodè.

  4. A ó yí gbogbo ilẹ̀ padà bi pẹ̀tẹ́lẹ̀ kan láti Geba dé Rimoni lápá gúúsù Jerusalẹmu: yóò di bí aginjù, ṣùgbọ́n a ó sì gbé Jerusalẹmu sókè, yóò sì gbe ipò rẹ̀, láti ibodè Benjamini títí dé ibi ibodè èkínní, dé ibodè igun nì, àti láti ilé ìṣọ́ Hananeli dé ibi ìfúntí wáìnì ọba.