Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Feast of the Passover: The first sheaf of barley harvest offered the day after the Sabbath in
Àwọn ẹsẹ nípa The first sheaf of barley harvest offered the day after the Sabbath in
“Sọ fún àwọn ará Israẹli, kí o sì wí fún wọn pé, ‘Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ tí èmi yóò fún yín, tí ẹ bá ń ṣe ìkórè, kí ẹ mú síírí ọkà àkọ́kọ́ tí ẹ kórè wá fún àlùfáà.
Kí ó fi síírí ọkà náà níwájú Olúwa, kí ó le jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún yín: kí àlùfáà fì í ní ọjọ́ kejì ìsinmi.
Ní ọjọ́ tí ẹ bá fi síírí ọkà náà, kí ẹ mú ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan láìní àbùkù rú ẹbọ sísun sí Olúwa.
Pẹ̀lú ọrẹ ọkà rẹ tí ó jẹ́ ìdá méjì nínú mẹ́wàá òsùwọ̀n efa (èyí jẹ́ lita mẹ́rin ààbọ̀) ti ìyẹ̀fun, tí a fi òróró pò ọrẹ tí a fi iná ṣe fún Olúwa òórùn dídùn pẹ̀lú ọrẹ ohun mímu rẹ̀ tí í ṣe ìdámẹ́rin òsùwọ̀n hínì (èyí jẹ́ lita kan).
Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ àkàrà kankan tàbí kí ẹ sun ọkà tuntun títí di ọjọ́ tí ẹ fi mú ọrẹ yín wá fún Ọlọ́run yín. Èyí ni ìlànà ayérayé fún ìran tí ń bọ̀, níbikíbi tí ẹ bá ń gbé.