Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Euphrates: Captivity of Judah represented by the marring of Jeremiah's girdle in
Àwọn ẹsẹ nípa Captivity of Judah represented by the marring of Jeremiah's girdle in
Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá nígbà kejì,
“Mú àmùrè tí o rà, kí o sì fiwé ẹ̀gbẹ́ rẹ, kí o sì lọ sí Perati, kí o lọ pa á mọ́ sí pàlàpálá òkúta.”
Nígbà náà ni mo lọ pa á mọ́ ní Perati gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti wí fún mi.
Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, Olúwa sọ fún mi, “Lọ sí Perati kí o lọ mú àmùrè tí mo ní kí o pamọ́ síbẹ̀.”
Nígbà náà ni mo lọ sí Perati mo lọ wá àmùrè mi níbi tí mo pa á mọ́ sí, ṣùgbọ́n nísinsin yìí àmùrè náà ti bàjẹ́, kò sì wúlò fún ohunkóhun mọ́.
Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá pé:
“Èyí ni ohun tí Olúwa sọ: ‘Bákan náà ni èmi yóò run ìgbéraga Juda àti ìgbéraga ńlá ti Jerusalẹmu.