Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Death of the Wicked
Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì
Sedekiah jẹ́ ẹni ọdún mọ́kànlélógún nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mọ́kànlá.
Ó sì ṣe búburú ní ojú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, kò sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú Jeremiah wòlíì ẹni tí ó sọ̀rọ̀ Olúwa.
Ó sì tún ṣọ̀tẹ̀ sí ọba Nebukadnessari pẹ̀lú, ẹni tí ó mú kí ó fi orúkọ Ọlọ́run búra. Ó sì di ọlọ́run líle, ó sì mú ọkàn rẹ̀ le láti má lè yípadà sí Olúwa, Ọlọ́run Israẹli.
Ẹ̀rù ńlá yóò bà á ní ìhà gbogbo, yóò sì lé e dé ẹsẹ̀ rẹ̀.
Àìlera rẹ̀ yóò di púpọ̀ fún ebi, ìparun yóò dìde dúró sí i nígbà tí ó bá ṣubú.
Yóò jẹ ẹ̀yà ara rẹ̀; ikú àkọ́bí ni yóò jẹ agbára rẹ̀ run.
A ó fà á tu kúrò nínú àgọ́ tí ó gbẹ́kẹ̀lé, a ó sì mú un tọ ọba ẹ̀rù ńlá nì lọ.
Yóò sì máa jókòó nínú àgọ́ rẹ̀ èyí tí í ṣe tirẹ̀; sulfuru ti o jóná ni a ó fún káàkiri ibùgbé rẹ̀.
Ọlọ́rọ̀ yóò dùbúlẹ̀, ṣùgbọ́n òun kì yóò túnṣe bẹ́ẹ̀ mọ́, nígbà tí ó bá la ojú rẹ̀, gbogbo rẹ̀ a lọ.
Ẹ̀rù ńlá bà á bí omi ṣíṣàn; ẹ̀fúùfù ńlá jí gbé lọ ní òru.
Ẹ̀fúùfù ìlà-oòrùn gbé e lọ, òun sì lọ; àti bí ìjì ńlá ó sì fà á kúrò ní ipò rẹ̀.